O MA ṢE O; WỌN DANA SUN ỌMỌ NAIJIRIA LORILEEDE SOUTH AFRIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 30, 2019

O MA ṢE O; WỌN DANA SUN ỌMỌ NAIJIRIA LORILEEDE SOUTH AFRIKA

Ọpọ awọ ọmọ Naijiria ti wọn gbọ nipa bawọn ọmọ orileede South Afrika ṣe lu awọn ọmọ Naijiria meji kan lalubami laipẹ yi ni wọn barajẹ pupọ, paapaa bi wọn tun ṣe dana sun Samuel Nkennaya, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Ẹnikeji ti wọn lu toun wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii ni Chinonso Nwudo lọsibitu kan to ti n gba itọju.

Victor Ayanfe-Oyebanjo, tọ jẹ akọwe ẹka Mpumalanga fawọn ọmọ Naijria lo gbe ọrọ naa sita fawọn oniroyin laarọ onii.

ọkunrin naa ni ṣe lawọn eeyan yi lọọ kọlu Messrs Nkennaya ati Nwudo, ti wọn si fẹsun kan wọn pe wọn ji ọmọdun mẹfa kan gbe, lai mọ pe ọmọ Nwudo gan an ni wọn n sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI