Bawọn mọlẹbi oloogbe naa ṣe n gbera ṣanlẹ, bẹẹ lawọn kan n wa ẹkun mu, tawọn kan si barajẹ pupọ lọjọ Satide Abamẹta, ijẹta to kọja yi nibi ti wọn ti n fi eeru fun eeru, erupẹ fun erupẹ niluu ẹ, Tse Kutar Nyiev, to wa nijọba ibilẹ Guma ipinlẹ Benue.
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kẹtala oṣu yi ni Kutar ṣegbeyawo ibilẹ pẹlu ololufẹ ẹ, to si jẹ pe kayeefi niku ẹ jẹ lọjọ kẹrindinlogun to jẹ ọjọ kẹta igbeyawọ to ṣe. Ipinlẹ Zamfara la gbọ pe oloogbe naa ti n sin orileede baba ẹ lọwọ.
No comments:
Post a Comment