Arabinrin Rofiat Ọladepo ati
Abdullahi Oladepo ti wọn jẹ iyawo ati ọmọ akọwe agba ileewe girama Ẹdẹ Muslim
Grammar School ni ilu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun ti gbe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria
lọ si ile ẹjọ lori ẹsun fifi ipa gbe ni si atimọle lọna aitọ.
Ni ọjọ aje ni wọn pẹjọ naa ni
ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun eyi to fi ikalẹ si ilu Ikirun.
Lara awọn ti wọn tun so pọ mọ
ẹjọ naa ni ọga agba ọlọpaa lẹkun kọkanla, AIG Zone XI, ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ati
amofin agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami lori ifidimulẹ ẹtọ wọn labẹ
ofin.
Bakan naa ni wọn tun beere fun
biliọnu kan naira gẹgẹ bii owo gba maa binu lori ẹsun fifi ipa muni lai tẹle
ilana ofin, fifini si ahamọ ati ifiya jẹni lọna aitọ.
Ni aipẹ yii ni iroyin gbee jade
pe awọn ọlọpaa mu awọn olupẹjọ naa si ahamọ lori ẹsun pe baale wọn, to jẹ akọwe
agba fun ileewe girama naa ṣe fun sẹnetọ Ademọla Adeleke ni iwe ẹri akẹkọjade
ileewe naa.
Awọn ọlọpaa n wadii Sẹnetọ
Ademọla Adeleke, oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun ninu idibo gomina ọdun to
kọja lori ẹsun ayederu iwe ẹri girama lọwọlọwọ.
- BBC
No comments:
Post a Comment