Ijọba ipinlẹ Eko lo fi ikilọ sita
fun awọn ara ilu pe ki wọn ṣọra lati maa jẹ awọn pọnmọ oloro kan to wa lọja
bayii.
Ijọba naa ni awọn ti mu eeyan
mẹta ti wọn n ta awọn pọnmọ yii ni ijọba ibilẹ Ọjọ ati Iba ti wọn si tun ko
awọn pọnmọ oloro wọnyii lori igba wọn.
Ninu atẹjade kan ti Kọmisana
eto ilera nipinlẹ naa Dokita Jide Idris fi sita, ijọba ipinlẹ Eko lawọn ti ''ko
awọn eeyan mẹta ti ọwọ tẹ lori pọnmọ oloro yii lọ si iwaju ile ẹjọ ti awọn si
ti fi awọn pọnmọ naa ranṣẹ si ile ayẹwọ ile iṣẹ NAFDAC ti yoo sọ boya wọn ṣee
jẹ''
Idris salaye ninu atẹjade naa
pe ijọba bẹrẹ si ni tojubọ ọrọ pọnmọ oloro yi lẹyin igba ti awọn kẹfin pe awọn kan
n ta pọnmọ ni ago mẹrin si ago mẹfa aarọ lawọn aaye kan ni Ọjọ ati Iba.
O wa kilọ f'aralu pe ki wọn ṣe
ayẹwo daada ki wọn to ra pọnmọ lọja ki wọn si tete ta awọn oṣiṣẹ ijọba lolobo
bi wọn ba funra si awọn ounjẹ kankan ti o ni kọnunkọhọ.
- BBC
No comments:
Post a Comment