NITORI IKỌSILẸ, PẸNDO POKUNSO LỌJỌ AJINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 23, 2019

NITORI IKỌSILẸ, PẸNDO POKUNSO LỌJỌ AJINDE

Ṣe ni gbogbo agbegbe Twon-Brass nipinlẹ Bayelsa fẹẹ le daru lọjọ Mọnde ana, ti i ṣe ọjọ Ajinde Jesu tawọn ẹlẹsin Kristẹẹni n ṣajọyọ lọwọ nigba tiwọn ri ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Pẹndo to so ara rẹ kọ sori igi, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Pẹndo ta a gbọ pe ọmọdun mẹtadinlọgbọn ni ni wọn sọ pe ọrẹbinrin rẹ ti wọn jọ n fẹ ara wọn lati bi ọdun meloo kan sẹyin lo ṣẹṣẹ kọ ọ silẹ, to si gbe gbogbo igbesẹ lati ri i pe kawọn mejeeji tun maa pada fẹ ara wọn, ṣugbọn ti wọn loo ja si pabo.

Nigba ti ọrọ naa jẹ kayeefi ni wọn ni ọkan lara awọn Ẹgbọn Pẹndo tu aṣiri naa sita pe ọrẹbinrin rẹ lo kọọ silẹ, to fi gbe igbesẹ naa.

Wọn ni Pẹndo ti n gbiyanju lati salọ tabi pa ara rẹ danu, ṣugbọn ti wọn sọ pe awọn mọlẹbi ẹ n parọwa fun, to si mu ki wọn maa ṣọ ni gbogbo igba.

AWIKONKO gbọ pe ko sẹni to mọ igba ti Pẹndo yọ jade ninu ile, to si lọọ gbẹmi ara rẹ sori lọsan ana.

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn wa a gbe oku Pẹndo sọkalẹ, ti wọn si gbe e lọ si mọṣuari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI