Irọ nla ni o, ko si nnkan to jọ bẹẹ – Ganzallo ati Ọlanrewaju
Ẹnitan Emmanuẹl ati Adeṣina Ṣittu nibi ipade ti wọn ṣe laipẹ yi |
BỌSUN ỌLANIYI, ABẸOKUTA: Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe eto aabo nipinlẹ Ogun ṣetan lati gun oke agba ju ti tẹlẹ lọ, ki ifẹ ati irẹpọ si jọba laarin awọn ileeṣẹ eleto aabo naa.
Ohun ta a gbọ ni pe ipade ti n lọ loriṣiriṣi laarin awọn ọga agba ẹgbẹ Fijilante mẹtẹẹta nipinlẹ Ogun lati ri i pe awọn darapọ di ẹyọkan ṣoṣo lati tubọ ran ijọba to n bọ lọjọ kọkandinlọgbọ oṣu karun ọdun yi lọwọ.
Ki i ṣe ahesọ pe ẹgbẹ Fijilante mẹta lo wa nipinlẹ Ogun lọwọlọwọ bayii. Awọn naa ni Vigilante Service of Ogun State ti Kọmanda Soji Ganzallo jẹ ọga wọn; Vigilante Group of Nigeria ti Kọmanda Olanrewaju Nureni Adedoyin ti ọmọ Alaaji Muhammed Jahun lewaju wọn ati Vigilante Group of Nigeria tawọn ọmọ ẹyin Alaaji Alimọdu Ṣokoto.
Ibẹrẹ iṣejọba Gomina Amosun ni wahala to wa laarin wọn ti bẹrẹ, ṣugbọn lọdun bii mẹta sẹyin ni wahala naa tun gbọna min in yọ, to di pe onikaluku wọn duro lọtọọto.
Ṣugbọn ni bayii, AWIKONKO gbọ pe wahala naa ti n lọ si oko igbagbee bayii.
Ohun ta a gbọ ni pe Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun lo n gbiyanuju lati yanju aawọ to wa laarin awọn ẹgbẹ naa, to si ti sọ fun wọn pe ile kan ṣoṣo loun fẹẹ ba ṣiṣẹ, nitori naa, ki wọn pada si ẹsẹ aarọ ti wọn ti bẹrẹ.
Ọga agba ẹgbe VGN ẹkun ilẹ Yoruba, iyẹn Zonal Commander Southwest, ACG Ẹnitan Emmanuel ati Ọga agba lẹka ofin lẹkun ilẹ Yoruba, ACG Legal Southwest, ACG Shuiab Adeshina Shittu lo gbe ọrọ naa sita f’AWIKONKO lọjọ Tuside to kọja yi niluu Abẹokuta, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe lootọ ni awuyewuye ti a n gbọ.
Kọmanda Nureni Adedoyin, adari ẹgbẹ VGN nipinlẹ Ogun |
“Ibi ti a wa yi, ọfiisi wa to wa ni Aṣero yi ni ọfiisi ti olu-ileeṣẹ ẹgbẹ yi niluu Abuja fọwọ si, bi ẹnikẹni ba pe ara rẹ ni oṣiṣẹ VGn, iru ẹni bẹẹ gbọdọ ni orirun, mo si fẹ ki ẹ mọ pe gbogbo awọn to n pe ara wọn VGN lorileede Naijiria, abẹ Alaaji Alimọdu Ṣokoto to jẹ aṣoju iyẹn Ambasadọ fun ọrọ alaafia ni United Nation ti jade sita. Agbalagba ni baba naa bayii, o ṣi wa laye.
“Awọn kan le ro pe awọn gbọn ju ọgbọn funra rẹ lọ, eyi gan an lo fa iyapa ti ẹ n ri ninu VGN lonii. Ṣugbọn ni ti ipinlẹ Ogun ni bi, a n gbiyanju lati ko ara wa jọ pọ, lati ri i pe a ni ilepa kan naa, paapaa julọ nigba ti Gomina tuntun yi ko fẹẹ ri awọn to n tan ara wọn jẹ.
“Mo fẹẹ gbagbọ pe ẹgbẹ meji lo wa nigba ti Gomina Ibikunle Amosun de ijọba to n kasẹ nilẹ lọ yi, awọn nnkankan lo ṣẹlẹ to fi ni koun da Vigilante Service of Ogun state silẹ. Bi ẹ ba si wo o, ẹ ma a ri i pe ilepa ati afojusun ẹni to da VGN silẹ yatọ patapata, ko si ipa ẹ ninu nnkan ti a n pe ni VSO, ayafi bi a ba fẹ ẹ tan ara wa jẹ.
“Niisin yi, ti Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ti sọ pe apapọ ẹgbẹ VGN loun fẹẹ ba ṣiṣẹ pọ, mo fẹẹ fi da gbogbo awọn to ni etiigbọ loju pe lasiko yi, wọn maa ri ayipada rere latinu ẹgbẹ VGN. Ni ipele ti a de yi, a n gbiyanju lati tun ile wa ṣe, nitori pe bi a ko ba tun ile wa ṣe, ko le ṣee ṣe fun ẹnikan lati sọ pe oun fẹẹ bawọn eyan layika ṣe pọ. A fẹẹ ri i pe a mu awọn to ti yapa pada wa, ati pe nitori pe a ni olu-ileeṣẹ VGN to wa niluu Abuja, eyi ti Alaaji Ali Ṣokoto jẹ adari ẹ, bẹẹ la si tun ni awọn to yapa ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Alaaji Jahun.
“Ẹgbẹ ti Jahun to yapa lo bi Ọgbẹni Nureni Adedoyin nipinlẹ Ogun, bo tilẹ jẹ pe ẹjọ naa ṣi wa nile ẹjọ kotẹmilọrun, ṣugbọn eyi ki n ṣe nnkan ti a sọ lasiko yi, ọmọ iya la jẹ, ti a si jade lati inu ẹbi kan naa, a si fẹẹ ri i daju paapaa nipinlẹ Ogun pe a di ẹyọkan ṣoṣo pada ninu VGN.
“Emi ni mo n bawọn to yapa sọdọ Alaaji Jahun ti Ọgbẹni Ọlanrewaju jẹ adari wọn nipinlẹ Ogun sọrọ pe ki wọn jẹ ka fọwọsowọpọ, ko si ma wahala kankan mọ fun ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni Fijilante, ka si le so eso rere.
Soji Ganzallo, ọga agba VSO nipinlẹ Ogun |
“Gbogbo ẹni to ba wa, to ba ti jẹ ọmọ ipinlẹ Ogun la maa gba laaye nitori pe ojo ni wa, a ko ba ẹnikẹni ṣe ọta. Agan niṣẹ eto aabo, ko ṣe ẹ da gbe, paapaa julọ awọn to walabẹ Ọgbẹni Nureni Adedoyin, wọn yapa ni, a si mọ pe nigba ti Gomina to n bọ ti sọ pe ile kan ṣoṣo loun fẹ fun VGN, o di dandan ki wọn pada wa sile, a ko si ta ẹnikẹni danu gẹgẹ bi ọmọ ipinlẹ Ogun.
Nigba ti wahala awọn agbaa loke ko tii yanju, bawo ni ti ipinlẹ Ogun yoo ṣe yanju?
“A ti ri ọpọlọpọ ipinlẹ, paapaa julọ bi a ba pin gbogbo Oke-Ọya si mẹwaa, o fẹ ẹ le jẹ pe mẹsan an ataabọ lawọn eeyan wa to wa nibẹ, ti wọn si pawọpọ nitori anfaani ilu wọn. Nnkan ti a fẹ ẹ ṣe nipinlẹ Ogun kii ṣe tuntun, awọn ipinlẹ ti mo n sọ yi bẹrẹ lati Kwara lọ soke titi de Borno, gbogbo nnkan to da wọn pọ nijọba wọn n fun wọn.
“iru ẹ ṣẹlẹ lọdun bi i meje sẹyin nigba ti Gomina Amosun de bẹ, to sọ pe ka parapọ nitori pe ki i ṣe Gomina lo mu orukọ VSO jade, Ọgbẹni Akinduro to jẹ igbakeji kọmiṣana ọlọpaa to ti fẹyinti lo jẹ oludamọnran lori ọrọ eto aabo nigba naa lo mu orukọ naa fun wọn. Nnkan to fa wahala nigba naa ni pe, wọn ni ka jẹ orukọ kan naa, a si sọ fun wọn pe orukọ to ni iwe aṣẹ la maa jẹ, iyẹn ni VGN, a ko ni i jẹ VSO, nitori pe ko si ofin to tẹle orukọ yẹn.
“Awọn to wa nibẹ nigba yẹn, wọn ko gba fun idi to ye awọn nikan ṣoṣo. Gbogbo mọto ati ẹtọ to yẹ ko tọ si wa ni wọn pin fawọn ọlọpaa, ṣọja, kọsitọọmu, sifu sifẹnsi abbl., wọn fun wa nigba naa pe awọn ko le gbe ẹgbẹ kan ṣoṣo to pin larugẹ, ati pe bi a ko ba gba lati jẹ orukọ kan to ni ofin ninu, awọn ko ni i fun wa ni nnkankan. Gbogbo mọto ti ẹ n ri nidi awọn VSO lo jẹ pe eyi ti ijọba ana, iyẹn ijọba Gbenga Daniel fun VGN ni.
“Ki iru ẹ ma ba a tun un ṣẹlẹ la ṣe gbe igbesẹ pe ka fimọ ṣọkan, ti a si ri i pe awọn to yapa sọdọ Adedoyin ti n sare wa, tawọn VSO si ti n pada wa ba wa. O si di dandan ka tẹle ofin, bi wọn ba wa, aaye ṣi silẹ fun wọn, bi wọn ko ba si wa, o ku si wọn lọwọ, awako le lọọ ba wọn. Bi mo ṣe n sọrọ yi, iwe wa ti wa niwaju Aarẹ Buhari, ko fọwọ si i lo ku. Ju gbogbo ẹ lọ, nnkan ti a n sọ ni pe ka pawọpọ lati gbe ilu wa soke.”
Ṣugbọn nigba to n fesi, Ọga VSO nipinlẹ Ogun, Kọmanda Soji Ganzallo sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara, irọ to jinna si otitọ ọrọ lasan ni. O ni ile igbimọ aṣofin ti bu ọwọ lu iwe abadofin ẹgbẹ VSO, fun idi eyi, ẹgbẹ awọn ko tun le parapọ pẹlu ẹgbẹ min in lailai
Bakan naa, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju ni ti ẹ naa tun jẹ ko ye wa pe ko si otitọ ninu ọrọ naa rara, oju rere lawọn to sọrọ naa n wa kaakiri nitori pe nkan ti wọn maa jẹ ni wọn n wa.
No comments:
Post a Comment