Ni nnkan bi
aago meje aabọ aarọ ọjọ Sande ana la gbọ pe Ṣeun ati ọrẹ ẹ ti wọn pe ni Ojo Ibẹru
ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ okunkun Aye la gbọ pe wọn da ọlọkada kan duro, nibi tiyẹn
si ti fẹẹ gbe wọn ni wọn ti yọ ibọn si i.
Ariwo ti wọn
ni ọlọkada naa pa lo mu kawọn ara agbegbe naa sare debẹ, ti ọwọ si tẹ Ṣeun, ṣugbọn
to ṣeni laanu pe ekeji ẹ, Ojo raaye na papa bora.
Awọn ara
adugbo naa la gbọ pe wọn mu Ṣeun lọ teṣan ọlọpaa ẹkun Agbado, nibẹ lo si ti jẹwọ
fun wọn pe iṣẹ adigunjale loun fi n jẹun.
Ni bayii, Kọmiṣana
ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Baṣhir Makama ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa SARS mu Ṣeun lọọ jẹ
igbadun diẹ lọdọ wọn, ko too di pe wọn foju ẹ bale ẹjọ, bẹẹ lo sọ pe ki wọn
gbiyanju lati ri Ojo to na papa bora naa mu.
No comments:
Post a Comment