NI INDIA, WỌN MU AGBABỌỌLU NAIJIRIA PẸLU OBITIBITI KOKEENI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 17, 2019

NI INDIA, WỌN MU AGBABỌỌLU NAIJIRIA PẸLU OBITIBITI KOKEENI

Pẹlu bi nkan ṣe n lọ yi, afaimọ ni ki ọkan lara awọn agbabọọlu ọmọ orileede Nigeria to fi orileede India ṣebugbe ma pada lo eyi to ku nigbesi aye ẹ lọgba ẹwọn pẹlu bọwọ awọn ọlọpaa se tẹ lai pẹ yi pẹlu obitibiti egbogi oloro, iyẹn kokeeni to gbe fi ṣowo.

Yatọ si ẹsun ti wọn ka agbabọọlu naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Ikenna l'ẹsẹ yi, wọn ni se lo tun n gbe orileede naa pẹlu iwe irinna tọjọ ti lọ lori ẹ.

AWIKONKO gbọ pe iwọn kokeeni ti ko din ni 10grams ni wọn gba lọwọ lasiko ti aṣiri rẹ tu.

Mumbai la gbọ pe Ikenna ti n ko kokeeni naa bo, tasiri ẹ si tu s'ọwọ ọlọpaa lasiko ti wọn ṣiṣẹ aabo kọja lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI