Bo tilẹ jẹ oun tawọn kan n sọ tẹlẹ ni pe ahesọ lasan ni pe Ọba Fọlagbade Ọlatẹru Ọlagbegi, Ọlọwọ tiluu Ọwọ nipinlẹ Ondo ti waja, ṣugbọn AWIKONKO n fi asiko yi muu da gbogbo awọn to ṣin ṣiyemeji lori iroyin naa bayii pe lootọ ni.
Ọjọ Tuside to kọja yi la gbọ pe Kabiyesi naa gbọ ipe awọn baba nla rẹ, to si jẹ wọn latari aisan ọjọ ogbo to da a dubuẹ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
Ọba Olagbegi ku lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77years).
Ọdun 2003 ni Kabiyesi Fọlagbade gba ade gẹgẹ bi Ọlọwọ tiluu Ọwọ labẹ ijọba Gomina Ṣẹgun Agagu nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment