Gbogbo eto lo ti pari bayii
lori ayẹyẹ ọjọọbi ọdun mọkandinlaadọta (49) ti Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Iba
Gani Abiọdun Adams fẹẹ ṣe laipẹ yii.
Gbọngan ayẹyẹ nla ti Times Square Event
Centre, n’Ikẹja, l’Ekoo layẹyẹ pataki yii yoo ti waye, nibi ti awọn
lade-lade ati loye-loye yoo ti peju, ti ẹsẹ yoo pele paapaa lati ṣẹyẹ nla fun akọni ọmọ Yoruba yii.
Ninu atẹjade ti oluranlọwọ eto
iroyin fun Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Alaaji Kẹhinde Aderẹmi fi sita, eyi ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo
ti sọ pe, “Ayẹyẹ yii maa larinrin, bẹẹ ni gbọngbọn yoo kan si i pẹlu. Ayẹyẹ ọdun
mọkandinlaadọta ni Aarẹ Iba Gani Abiọdun Ige Adams fẹ ẹ ṣe.
Gbogbo eto pata lo si ti to. A fẹẹ ba aṣaaju wa yọ, a fẹẹ ba olori wa ṣẹyẹ nla,
bẹẹ lawọn ẹbi, ara, ọrẹ, ẹgbẹ OPC ati OPU lapapọ atawọn ojulumọ ti n mura gidigidi
lati peju pesẹ sibi ayẹyẹ nla ọhun.”
O fi kun un wi pe, Gbogbo eeyan
pata la pe o, ẹyin ojulowo ọmọ Yoruba, ẹ wa, ẹ jẹ ka jọ ṣẹyẹ nla fun olori wa. Ọjọ ọhun n sunmọ, bẹẹ ni gbogbo eto lo ti n to, ti a n mura kẹtikẹti lati ba
oloriire ọmọ Yoruba yọ, ati pe ayẹyẹ nla ti yoo mi ilu titi lọdun yii ni. A n
reti yin o, awa paapaa naa n mura nnkan alejo silẹ daadaa.”
No comments:
Post a Comment