Lẹ́yin oṣu karun un ti igbimọ kan ti ijọba apapọ gbe
dide lati wadii ẹsun aṣemaṣe ati jẹgudujẹra ti wọn fi kan ọga ajọ NHIS Usman
Yusuf Usman Yusuf, Aarẹ Muhammadu Buhari ko ti i gbe igbesẹ lori abajade iwadii
igbimọ naa.
Igbimọ naa sọ ninu abajade rẹ pe ki ileeṣẹ aarẹ yọ
akọwe agba ajọ adojutofo ilera Naijiria (NHIS) naa nipo.
Ṣugbọn iroyin fihan pe aarẹ ko ti i gba iṣẹ́ lọ́wọ́
Yusuf bo ti lẹ ni pe ko lọ simi diẹ nigba ti wọn gbe igbimọ naa kalẹ ni oṣu
kẹwaa, ọdun 2019.
Iroyin fihan pe abajade naa ti tẹ aarẹ lọwọ lati oṣu
kejila, ọdun 2018.
Abajade naa jade lẹyin oṣu keji ti ijọba apapọ gbe
igbimọ ẹleni meje naa dide.
Igbimọ naa ni Yusuf ru ofin to n ṣe akoso bi wọn ṣe
n gbe iṣẹ jade labẹ ijọba ati ofin to n dari ileeṣẹ ijọba.
Aarin Yusuf ati Minisita fun Eto Ilera, Ọjọgbọn
Isaac Adewole ko wọ lẹyin ti minisita ni ko lọ rọkun nile lori ẹsun jẹgudujẹra
owo to din diẹ ni biliọnu kan naira ti wọn fi kan Yusuf.
Ni kete lẹyin rẹ ni ileeṣẹ aarẹ da a pada sipo.
Eyi mu ki ọpọ eeyan maa bere pe ki gan an lo wa
laarin aarẹ ati ọjọgbọn Usman Yusuf?
Nigba naa lọun, Ọjọgbọn Yusuf ni ko si ohun ikọkọ
kan laarin ohun ati aarẹ ati pe ilana ofin ni aarẹ n tẹlẹ eleyi to fidi rẹ mulẹ
wi pe igbimọ tabi minisita ko lee yọ oun bi ko ṣe aarẹ.
Ọjọgbọn Usman Yusuf ni awọn eeyan ti wọn n lo owo
ara ilu lati lu jibiti lẹka naa ni wọn n fin ina mọ oun nidi.
Lẹyin rẹ ni igbimọ to n ṣe akoso ajọ NHIS tun ni ki
Yusuf lọ rọkun nilẹ.
Ni bayii, igbimọ ti ijọba apapọ gbe dide ti ni ki
gbogbo ọmọ igbimọ alakoso NHIS naa maa lọ ile wọn.
Gbogbo igbiyanju ile iṣẹ BBC lati ba ijọba sọrọ lori
koko yii ni ko tii bi eso to yẹ.
- BBC YORUBA
- BBC YORUBA
No comments:
Post a Comment