Bọya lẹ mọ pe oni, ọgbọn ọjọ oṣu kẹrin ọdun 2019 lo pe ọdun mẹrindinlogun ti gbajugbaja sọrọsọrọ nni, ẹni tawọn sọrọsọrọ onii n wo gẹgẹ bi awokọṣe, Oloogbe Elijah Oluwagbemiga Adeboye, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si: Alaaji-Pasitọ-Oluwo, Abẹfẹ, Jengbetiele, Itu Baba-Ita, Alaye mi Gbengulo dagbere faye pe o digboṣe.
Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò
lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to
gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.
Lárá àwọn iṣẹ́ ti Gbenga
Adeboye ti ṣe ni Ọmọ Majẹmu, Ọrọ Ṣunukun 1&2, Ph.D Beetle, Fúnwọntán
1&2, Ọrọ láti orí ìtẹ́ mímọ 1&2, Versatility, Aiyetoto,
Controversy, Supremacy, Ijinlẹ, Laisi Abesupinlẹ atawọn min in ta a ko ranti dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
AWIKONKO n fi asiko yi ṣe iranti akọni, ti ko le ku lailai naa, nitori pe iṣẹju-iṣẹju lo fi lọkan gbogbo eeyan, ti wọn mọn-ọn, atawọn ti ko rii ri.
No comments:
Post a Comment