Lẹyin oṣu marun ti Arabinrin Ọlajumọkẹ di Olori laafin Olodogbo tillu Odogbo-Ijẹṣa nipinlẹ Ọṣun, Ọba Ọlatunde Ọginni, iyalẹnu lọrọ iku ojiji to ṣalabapade ṣi n jẹ fawọn to gbọ nipa ẹ.
Alakoso ẹkun South West fun ileeṣẹ Nigeria Broadcasting Commission, NBC ni Oloogbe Ọlajumọkẹ Ọginni ko too jade laye lọjọ Tuside ọsẹ to kọja yi.
Ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2019 ni Ọba Ọlatunde Ọginni ṣe igbeyawo pẹlu Oloogbe, Olori Ọlajumọkẹ ni Ibadan North-West Registry to wa ni Onireke, Ibadan.
Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi lawọn eeyan ṣi n ṣe idaro oloogbe naa, nitori ta a gbọ pe eeyan to ko eeyan mọra ni Oloogbe naa.
No comments:
Post a Comment