Nigba to n
gbe iwe aṣẹ naa le ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ, iyẹn DSS lọwọ nile ẹjọ lonii, Onidajọ
Husseini Baba-Yusuf sọ pe dandan ki ọkunrin naa yọju lati wa a sọrọ lori ẹjọ to
n jẹ lọwọ, di po ko ma a fa idiwọ fun igbeṣẹ ile ẹjọ.
Bẹ o ba
gbagbe, lara ẹsun ti wọn fi kan Dasuki ni pe o ṣe owo eto aabo kumọ-kumọ, bẹẹ
lo si tun da alaafia orileede Naijiria laamu. Dasuki pẹlu ọga agba ajọ NNPC tẹlẹ,
Aminu Baba Kusa, Acacia Holdings ati Reliance Referral Hospital lawọn tọrọ naa
tun kan.
No comments:
Post a Comment