IKU ỌBA ỌLAGBEJI ṢI N DABI ALA NI - ỌBASANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 19, 2019

IKU ỌBA ỌLAGBEJI ṢI N DABI ALA NI - ỌBASANJỌ

Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe iku Ọba Fọlagbade Ọlatẹru Ọlagbegi, tii ṣe Ọlọwọ tiluu Ọwọ nipinlẹ Ọṣun to waja lọjọ Tuside to kọja yi ṣi n dabi ala loju oun nitori pe ẹni ti ipa to ti ko lawujọ ko ṣe e gbagbe.

Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ naa lonii lati ẹnu oludamọnran ẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni kẹhinde Akinyẹmi.

Ọbasanjọ ni kii ṣe iru asiko bayii lo yẹ ki Ọba Ọlagbegi waja nitori pe asiko ti orileede Naijiria nilo rẹ julọ re e fun amọnran ati iriri nla rẹ to kun fun ọpọlọpọ ọgbọ to le mu idagbasoke alaragbayida de ba orileede yi.

Nitori naa, o ki gbogbo awọn Oloye atawọn olugbe ilu Ọwọ patapata ku arafẹraku, ati pe ki wọn ṣe ara giri, bẹẹ lo ni oyẹ ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iru eeyan ti Oloogbe naa jẹ ko to o papoda.

Aarẹ tẹlẹri naa wa a ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi aṣiwaju aṣa ninu awọn ọba alaye nile Yoruba, paapaa lorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI