Ajọ JAMB ni ko tii si gbedeke
fun ọjọ ti esi idanwo aṣewọle si ileewe giga UTME lọọkan.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC news
Yoruba, alukoro fun ajọ JAMB, Ọjọgbọn Benjamin Fabian ṣalaye pe, loots ni ajọ
naa ti bẹẹrẹ gbogbo igbesẹ ti o yẹ ko ṣaaju ijade awọn esi idanwo awọn akẹkọ
naa ṣugbọn ko tii lee sọ ni pato ọjọ ti esi naa yoo jade.
Ọjọgbọn Fabian tun fi kun un pe
lasiko ti esi yii ba jade, gbangba laṣa ta ni wọn yoo fi ṣe ati pe gbogbo akẹkọ
toi ṣe idanwo naa ni wọn ti fi ọna ti wọn yoo gba ri esi wọn ṣọwọ si.
Benjamin tun kilọ fun awọn to
se idanwo JAMB lati ri wi pe wọn sọ nọmba ti wọn fi se iforukọsilẹ, ki awọn
onijibiti ma ba a lu wọn ni jibiti.
O fikun wi pe awọn onijibiti
naa le e mu nọmba ẹrọ ilewọ wọn lati fi gba owo lọwọ wọn pẹlu adehun pe wọn yoo
fun wọn ni esi idanwo to dara ninu idanwo JAMB.
Ajọ JAMB naa wa parọwa si awọn
lati ri wi pe wọn tọju awọn ohun to se pataki si esi idanwo wọn bii nọmba ti
wọn fi se iforukọsilẹ.
- BBC
No comments:
Post a Comment