Gbogbo
eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ onibẹta ti ẹgbẹ awọn to n ta Patako
nipinlẹ Ogun, iyẹn Planks Sellers Association of Nigeria, ẹka ti Ẹgba Zone fẹẹ
ṣe lọjọ Tọside ọsẹ yi, iyẹn ọjọ kẹrin oṣu karun un.
Ayẹyẹ
naa ta a gbọ pe o ṣee ṣe ki ẹsẹ ma gba ero lori gbagede ti ileewe girama,
Rẹfurẹndi Kuti (Reverend Kuti Memorial Grammar School) to wa ni Isabọ,
Abẹokuta, nitori ta a gbọ pe awọn eeyan jankan-jankan ni wọn ti n gbaradi lati
farahan nibẹ.
Gẹgẹ
b'AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ni ọna mẹta ti ayẹyẹ naa yoo pin si ni wọn ti fẹẹ gbe
ọpa aṣẹ fawọn oloye tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, ti wọn si fẹẹ fi oye tuntun dawọn
eeyan pataki-pataki lọla, bẹẹ ni wọn tun fẹẹ ṣe ikowojọ lori akanṣe iṣẹ ti wọn
fẹẹ dawọ le.
Gẹgẹ
bi alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Oloye Dọlamu Adeniji Joseph ṣe ṣalaye
f'AWIKONKO, o ni gbogbo eto lo ti pari ati pe eto aabo to peye wa ni sẹpẹ fawọn alajo ọjọ naa.
Bakan naa nigba to n sọrọ lori bi wọn ṣe fimọ-ṣọkan, o ni “Ko si ọna ta a n gba bi ko ṣe
ẹsẹ tawọn baba wa gbe, tawa naa n tẹlẹ lọ, iyẹn ilana ta a fi n ṣe ẹgbẹ, bo ṣe
jẹ pe Ẹgba Zone ni ti wa yi, a tun pin ara wa si ọna mẹrin bii Owode Ẹgba,
Lafẹnwa, Ijaye ati Adatan, to si jẹ pe gbogbo wọn ni wọn tun ni alaga wọn to n
jẹ aṣoju lati fi ko ara wa jọ.
“Labẹ awọn ẹka wọnyii, a tun ni
isọri, tawọn naa tun ni oloye ti wọn, ti wọn si n ṣe ipade, eyi ko jẹ ki wahala
kankan wa. Ilana ta a fi n ṣe ẹgbẹ yi dara pupọ, bẹẹ naa ni eto n lọ bo ṣe yẹ.”
Lara awọn ti yoo wa nibẹ ni Gomina
Ibikunle Amosun; Ọnọrebu Lanre Ẹdun to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti wọn
ṣẹṣẹ dibo yan; Alaaji Sulaiman Omidina to jẹ alaṣẹ ileeṣẹ Slaab Motors ti wọn
fẹẹ fi ṣe Baba Ẹgbẹ; Alaaji Adeoluwa Mayegun to nileeṣẹ Tọnados ni Sagamu.
Awọn ọba alaye, Baalẹ atawọn
oloye loriṣiriṣi naa ko nii gbẹyin lọjọ naa, nigba ti Alaṣe ati apaṣẹ ileeṣẹ Kasilat
Ventures; Alaaji YahLateef naa yoo di oludamọnran ẹgbẹ yi. Alaaja F.A Jimoh ni
iya ọjọ naa. Alaaji Jelili Onifade ni Chief Launcher.
Nigba to n sọrọ nipa awọn to le
darapọ mọ ẹgbẹ naa, o lawọn to ba ni iwe ẹri ni wọn yege lati darapọ mọ ẹgbẹ
naa.
No comments:
Post a Comment