Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti ṣeleri fun Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọba Dapọ Abiọdun lati gbe ijọba silẹ fun un lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun to n bọ yi.
Oni ni Gomina Amosun fidi ẹ mulẹ lati ẹnu akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Taiwo Adeoluwa lasiko ti igbimọ ti yoo ṣagbatẹru gbigbe ipo silẹ loṣu to n bọ n gba awọn igbimọ ti yoo ṣe kokaari igba ipo tuntun ti Ọmọba Dapọ Abiọdun yan.
Ipade naa lo waye nileeṣẹ ijọba, to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Amosun jẹ ko di mimọ pe lati oṣu kejila ọdun to kọja loun ti yan igbimọ naa, to si di dandan ki wọn ṣe iṣẹ toun yan wọn fun bi asiko ba to.
Yatọ si eyi, Gomina Amosun tun fi ye igbimọ Ọmọba Dapọ Abiọdun yi ti igbakeji rẹ, Arabinrin Nọimọt Salakọ Oyedele ṣaaju wọn lọ pe bi Gomina tuntun naa ba ṣetan lati ko ẹru ẹ sile ijọba, aaye ṣi silẹ fun nitori pe gbogbo eto lo ti pari.
"Awa la maa seto akọsilẹ eto gbigbe ijọba silẹ lọna to lapẹẹrẹ fun un yin lọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2019.
"Lagbara Ọlọrun, lọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un yi, a maa lanfaani lati jokoo bayii, ka si gbe ijọba silẹ fun yin. A ko le sun lati rii pe ko si idiwọ lọjọ naa.
"A ti palẹmọ ile ijọba to wa ni Oke-Igbein, bi ẹ ba fẹẹ ko sinu ẹ ni ọla. Ati ile Aarẹ (Presidential Lodge) ati ile ijọba la ti palẹmọ wọn fun un yin. Bi ẹ ba sọ fun wa pe ẹ nilo awọn kọkọrọ awọn ibi mejeeji yi, a ṣetan lati ko wọn silẹ fun yin."
No comments:
Post a Comment