GANI ADAMS JU BỌNBU ỌRỌ LU FẸMI ADEṢINA NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 22, 2019

GANI ADAMS JU BỌNBU ỌRỌ LU FẸMI ADEṢINA NITA GBANGBA

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ Aarẹ orileede Naijiria, Ọgagun Muhammadu Buhari ni Aarẹ Ọna Kakanfọ, Iba Gani Adams pade laipẹ yii, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina lorukọ ọkunrin naa n jẹ, gbajugbaja oniroyin ni, bẹẹ lawọn eeyan fẹran ẹ daadaa, ti wọn si maa n gbadun ohun to ba kọ sinu iwe iroyin.
 
Oṣiṣẹ ileeṣẹ iwe iroyin The Sun ni, ko too gba iṣẹ lọwọ awọn Buhari. Nibi ti wọn ti pade ọhun; nibi apejọpọ kan niluu Ikẹja l’Ekoo ni, bẹẹ gẹgẹ ni Gomina Kayọde Fayẹmi naa wa nibẹ pẹlu.

Nibẹ ni Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina ti lanu koto o, ohun ti ọga awọn oniroyin yii si sọ ni pe, “A fẹni ti ko ba loju, tabi to ti pinnu lọkan ara rẹ wi pe oun ko ṣetan lati ri ohun rere kankan ninu ijọba Buhari yii ni yoo sọ wi pe, ijọba naa ko ti i mu ayipada rere ba orileede Naijiria atawọn eeyan rẹ.   

O ni, “Lorileede yii loni-in, awa naa ti n fi nnkan ranṣẹ soke okun, eyi to fihan wi pe a ti ni in lọpọ yanturu, ki a too le maa taari ẹ soke okun.

Adeṣina sọ pe ẹka idokoowo wa ti ru gogo si i paapaa bi o ti ṣe foju han nipari ọdun 2017, ati pe ileeṣẹ ipin idokoowo Naijiria gan-an lo fẹsẹ mulẹ julọ lagbaye. Bakan naa lo tun sọ pe, ileeṣẹ to n ri si owo ori gbigba tun ti ni miliọnu marun-un awọn to n sanwo owo ori si apo ijọba bayii yatọ si ti tẹlẹ.

Bẹẹ gẹgẹ lo tun sọ pe owo tijọba apapọ ti na lori ohun amayedẹrun fẹẹ to tiriliọnu mẹta (2.7tn) naira. O wa kadii ọrọ ọhun nilẹ wi pe, “Ti eeyan ba sọ pe oun ko ṣetan lati ri ohun rere ti ẹnikan n ṣe, koda ki tọhun ba ya afọju, ki wọn si maa fi awọn ohun meremere ti ẹni naa n ṣe han an, sibẹ yoo sọ pe oun ko ri  naa ni.”

Ọrọ to sọ ree, nigba ti Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Iba, Gani Adams naa si gba ẹrọ agbagbe, iyalẹnu lo jẹ pe ṣe lo kọju si Fẹmi Adeṣina, ẹni ti i ṣe oṣiṣẹ Aarẹ Buhari, o si sọ fun un wi pe, “Ti ẹ ba pada si Abuja lọdọ Buhari, ẹ sọ fun wọn wi pe ebi n pa wa, iya gidi n jẹ ọmọ Naijiria.”

Iba tẹ siwaju wi pe, “Loootọ ni agbekalẹ yin dara, bẹẹ gẹgẹ lẹ jẹ olootọ eeyan, ṣugbọn pẹlu awọn alaye tẹ ẹ ṣe kalẹ yii, ohun to dara ju ni ki awọn eeyan to wa lẹsẹ-kuku, iyẹn awọn mẹkunnu, o yẹ ki wọn le jẹgbadun ijọba to wa lode yii. Kaakiri agbaye ni mo ti lọ, orileede ti mo ti de yoo le ni orileede mẹrindinlaadọta (46), bẹẹ ni mo mọ ohun meremere tawọn to n ṣe ijọba wọn lawọn ibi ta a lọ yii n gbe ṣe fawọn eeyan wọn.

Ohun to yẹ fawọn eeyan ni ki wọn ri ipa ijọba lara wọn, loju wọn ati ninu aye wọn, ki i ṣe ki wọn maa ka a ninu iwe iroyin tabi gbọ ọ lasan. Ohun to yẹ ki wọn o mọ ninu ilẹ ati lọdẹdẹ wọn ni.

 Aarẹ Adams fi kun ọrọ ẹ wi pe, nigba ti Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina n sọrọ, niṣe lọrọ ọhun n ya oun lẹnu, nitori ẹni ti oun mọ daadaa gẹgẹ bi ojulowo oniroyin ni, ti awọn eeyan maa n fẹran lati ka abala iroyin ẹ ninu iwe iroyin SUN, ṣugbọn ọrọ to sọ yii fi i han gẹgẹ bi agbefọba, ṣugbọn to ba ti pada si Abuja, o ni, “Ẹ sọ fun Buhari wi pe ilu ko fara rọ, ebi n pa awọn eeyan gidigidi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI