Kọniṣọna tẹlẹ fọrọ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ nipinlẹ Ogun,
Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ ti sọ ọ sita gbangba pẹ ẹtanu ni Gomina Ibikunle Amosun
fi ja ayẹyẹ ọdun Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn African Drum Festival gba lọwọ oun nitori pe nigba
toun gbe eto naa kalẹ, Gomina Amosun ko gba a wọle, ṣugbọn nigba to ri i bawọn
eeyan ṣe kan saara soun lẹyin ayẹyẹ naa, lo ba pinu lati gba eto naa kuro lọwọ
oun. Ẹ ka bi ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ naa ṣe lọ pẹlu akọroyin wa.
IBEERE: Njẹ a le mọ yin lẹkunrẹrẹ?
AWIKONKO: Orukọ temi ni Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ, mo ti figba kan ri jẹ olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, mo tun ti figba
kan ri jẹ Kọmiṣọna fun eto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, bẹẹ ni emi ni Kọmiṣọna fun
eto Aṣa ati irin ajo afẹ to ṣẹṣẹ fipo silẹ, iyẹn nipinlẹ Ogun kan ṣoṣo yi.
IBEERE: Oriṣiriṣi awuyewuye lo n
lọ nita pe wahala wa laarin ẹyin ati Gomina Ibikunle
Amosun lo jẹ ki ẹ kuro ninu ẹgbẹ rẹ, ṣe lootọ ni?
AWIKONKO: Wel, Owe Yoruba kan lo sọ pe, ‘Ogun ọmọde ko le ṣere fun ogun ọdun’asiko iyapa
yoo wa ṣa a ni, ko nii ṣe pẹlu iye igba ti ẹ fi jọ n ṣe ọrẹ bọ. Nkankan ni yoo ṣe
sababi b'onikaluku yoo ṣe lọ lọtọọtọ, ṣugbọn ni ti Gomina to ṣẹṣẹ n fipo silẹ yi
ati emi, nnkan bi ọdun bi ọdun mẹrinla sẹyin la pade, ati pe gẹgẹ bi iru eeyan
ti mo jẹ, mo jẹ ẹni kan to n bọwọ fun eeyan pupọ, bi mo ba si pinu lati kuro lẹyin
eeyan, ko si pe mo tun n boju wẹyin mọ. Wipe mo kuro lẹyin Sẹnetọ Ibikunle
Amosun jẹ nipa ilana mi (progressive).
Akọkọ ni pe, mo jẹ ẹni to nifẹ si ilọsiwaju, mi o kii ṣe ẹni to maa n binu fufu
(reactionary). Nipasẹ ibinu fufu ni wọn
fi da ẹgbẹ oṣelu APM silẹ, ko fẹsẹ mulẹ daadaa. Ironu igbẹyin ni, o si di
dandan ko kuna laipẹ. ṣe lo dabi owe kan to sọ pe ‘ile ti a ba
fi itọ mọ, iri lo ma wo o’. Igba diẹ lasan naa ni, wọn ko da a silẹ nipasẹ iṣotitọ, nitori naa, o gbọdọ
lọ, idi ni yii ti gbogbo awọn eeyan nipinlẹ Ogun fi kọ ẹyin wọn sii, lai nii ṣe
pẹlu iye ibo ti wọn sọ pe awọn ni. O fẹẹ jẹ pe idameji ibo ti wọn sọ pe awọn ni
lo jẹ pe eyi ti wọn fowo ra ni, ẹ ko le yọwọ fifowo ra ibo kuro ninu ibo ti wọn
ni.
Bi ẹ ba jẹ ẹni
to maa n gba agbegbe Ibara nibi ti Gomina Amosun kọ ile ẹ si, ẹ maa ṣakiyesi pe
ọsẹ meji sasiko idibo, ṣe ni ile Gomina Amosun dabi ibi ẹrọ tawọn eeyan ti n
gba owo, iyẹn ATM, gbogbo eeyan lo n lọ sibẹ lati lọọ gba owo nibẹ, iyẹn ko si jẹ nkan babara fun wa nitori pe ifẹ Ọlọrun ni yoo bori ifẹ ọkan
eniyan. Gomina Amosun ti rin jinna lati maa ṣebi Ọlọrun, mo si kilọ fun un
nigba naa pe ko yee ri ara rẹ gẹgẹ Ọlọrun.
IBEERE: Bawo gan-an ni Gomina
Amosun ṣe n ṣe bi Ọlọrun?
AWIKONKO: Bẹẹni, nipa bo ṣe n lọ kaakiri lati sọ fun gbogbo agbaye pe oun loun yoo fa
Gomina ti yoo gba ipo lọwọ oun kalẹ. To si tun n mu ẹni naa kaakiri pe ẹni ti
yoo maa ṣe Gomina le wọn lori ni yii. Ọpọ igba ni mo kilọ fun un nigba naa, ṣugtbọn
ko gbọ.
IBEERE: A tiẹ gbọ pe ọpọ nnkan lẹ
fi jin fun Gomina Amosun, ṣugbọn ṣe lo fi ibi ṣuu yin. Ṣe lootọ ni? Idi ni pe, bo ṣe muu yin kuro nilẹ to n ṣan fun wara ati oyin lọ silẹ
gbigbẹ.
AWIKONKO: Mi o gba iyẹn wọle pe o mu mi lọ silẹ gbigbẹ, nnkan to nii ṣe pẹlu iṣẹ
ijiyin ni. Bi ẹ ba wo o daadaa, ko yẹ ki ẹ ri gbigbe ti wọn gbe e yin lati ibi
kan sibo min in gẹgẹ bi ifiyajẹni. O le fẹẹ jẹ bẹ, ṣugbọn ẹ jẹ ki n fi ti
Bibeli ṣapẹẹrẹ fun yin. Awọn ẹgbọn Josẹẹfu ta a si oko ẹru lero wipe
yoo ku, ṣugbọn fun pe wọn ta a si oko ẹru gan an lo tun gbe ayanmọ ẹ soke, to
fi di Apaṣẹ. Eyi gan an lo lọ nibamu pẹlu nnkan to ṣẹlẹ si mi. Ewe kan ko le
jabọ lara igi ki Ọlọrun ma mọ nipa ẹ.
Lero ọkan
Gomina Amosun, o le dabi i pe oun fiya jẹ mi loju ẹ, ṣugbọn mo fẹ ki ẹ gba mi
gbọ pe mo ṣaṣeyọri nipa Kọmiṣọna fun eto Aṣa ati Irin Ajo Afẹ. Ko si bi wọn yoo
ṣe sọ itan Ayẹyẹ Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn African Drum Festival ti yoo pe lai darukọ
Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ.
IBEERE: Bi a ba wo o ninu itan,
ileeṣẹ eto ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ lo jẹ igi lẹyin ọgba fun iru aṣeyọri
yoo wun ti Gomina ba ṣe, eyi ti wọn ti yọ yin kuro. Latigba ti wọn ti yọ yin
kuro nileeṣẹ naa ko ti ṣe daadaa mọ. Ṣe ka sọ pe inu yin dun bi wọn ṣe yọ yin
ni?
AWIKONKO: Wel, ipinu atọkan wa niyẹn. Bi ẹ ba fi ara yin silẹ lati sin awọn eeyan, tabi ka
sọ pe wọn yan yin lati sin awọn eeyan, ẹ ni lati maa bọwọ fun gbogbo eeyan, o
si gbọdọ sẹtan lati ṣiṣẹ isin ni eyikeyi ọna to pọ. Ki la o ba maa sọ kani wọn
ko yan mi si ileeṣẹ eto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lakọkọ? Ki la o ba sọ to ba jẹ
pe ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ ni wọn kọkọ gbe mi si. ṣugbọn sibẹ, kani ibi ti
mo ti bẹrẹ naa niyẹn, ọpọ awọn eeyan ni wọn le ti ri awọn nnkan ti mo ti ṣe nibẹ
yẹn, eyi lo fa a to fi jẹ pe oriṣiriṣi nnkan lawọn eeyan tunmọ ẹ si i nigba ti
wọn gbe mi kuro nibẹ lọ si ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ, ṣugbọn ti mi o tiẹ rii
ro rara.
Fun pe wọn
gbe mi lọ si ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ tun fi kun orukọ mi ni, to si tun jẹ
ki n gba iyi kọja afẹnusọ. Ọpọ awọn eeyan ni wọn n wo o pe o ti tan fun mi, ṣugbọn
mo fi ayọ gba a, to si wa a jẹ nnkan ayọ fun mi lonii nitori pe mo duro lori ọrọ
ọlọrun ati itan Josẹẹfu. Nigba ti mo de ileeṣẹ ti ẹyin pe ni ilẹ gbigbẹ yi, mo
tun un ṣe, mo si sọ ọ di ilẹ ọlọra to n ṣan fun wara ati oyin. Ko si ijọba to n ronu jinlẹ ti yoo fọwọ kere Ayẹyẹ Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn
African Drum Festival. Adura ni mo n gba nigba ti a ṣe eyi to jẹ akọkọ iru ẹ lọdun
2016, mo kọkọ ro pe Gomina Amosun yoo daa duro pe a ko gbọdọ ṣe e nitori pe ko
fọwọ sii. Mo gboya lati sọ ọ nita gbangba faraye pe ko fọwọ sii, ṣugbọn nigba
to ri i bi nnkan ṣe n lọ nigba naa, o yi ọkan ẹ pada, eyi lo ṣe jẹ pe fun idi
kan to jẹ pe oun nikan lo ye, o gbe gbogbo eto naa kuro nileeṣẹ mi, eyi to ṣe
di ọla.
IBEERE: Pupọ ninu awọn nnkan ti ẹ
ṣe lo jẹ pe Gomina Amosun ko fiṣẹ ẹ yin yin bo ṣe tọ. Ati pe ṣe ka sọ pe ẹ
kabamọ pe ẹ ṣiṣẹ labẹ Gomina Amosun?
AWIKONKO: Rara, mi o kabamọ! Ẹ jẹ ki n lọ nipasẹ ofin. Fifiṣẹ yin eeyan lọna
to tọ, ẹ ni lati gbe e yẹ wo nibamu pẹlu ofin adehun. Pe wọn fiṣẹ yin yin naa fẹẹ fara pẹ ẹ. Bi ẹ ba n sọ nipa wipe boya wọn ko
fiṣẹ yin mi lori ọrọ olowo de, o ṣee ṣe ko jẹ bẹẹ. Ṣugbọn bi awọn to wa nita
ati kaakiri agbaye ba n gbe oṣuba kare fun un, ẹ maa ni ifọkanbalẹ, ẹ maa gbagbọ
daadaa, eyi gan an ti to oriyin lọtọ.
IBEERE: Fun igba akọkọ, wipe ẹ mu
ọpọ awọn orileede wa papọ, bawo ni iriri naa ṣe ri fun un yin?
AWIKONKO: Iyi nla gidi ni, o si fọkan mi balẹ pupọ, to si tun bu iyi ati ọla fun orukọ
mi. Eto ta a ṣagbekalẹ ẹ laarin oṣu mẹrin pere ni lai lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun
ninu. Mo ni igboya lati sọ bẹẹ. Awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ ni wọn ṣagbatẹru eto
naa. A ko le kọ itan Ayẹyẹ ọdun Ilu Ilẹ Afrika naa lai dupẹ lọwọ Ọlọrun, ka si gbe
oṣuba kare fun awọn ileeṣẹ kọọkan atawọn eeyan pataki-pataki, nitori pe nigba ti ijọba to wa nibẹ lọwọ yi ri i pe eto naa ko le so eso
rere, Ọlọrun gbe ogo ẹ dide. Mo bẹrẹ eto naa lai lọwọ ijọba ninu, ti mo si ri i
bẹẹ titi dasiko yi. Ijọba ko yẹ ko da si nnkan to ba ni i ṣe pẹlu ọrọ irin ajo
afẹ rara, wọn ko gbọdọ fi owo ṣagbatẹru eto naa, wọn kan gbọdọ pese aaye ti yoo
mu irọrun bawọn eeyan, ki wọn si gbe igbimọ ti yoo ran eto naa lọwọ dide, ki
eto iṣuna naa si wa latọdọ awọn araalu.
Nnkan ta a ṣe
lọdun 2016 ni pe, mo pe awọn ti wọn n ba mi ṣiṣẹ dide, a si fori-kori lori ọna
ti a fẹ ẹ gbe e gba, ti mo si jẹ ko ye wọn pe wọn ko gbọdọ jẹ kijọba lọwọ si i,
ṣugbọn ijọba yoo pese aye irọrun fawọn eeyan. A rasnṣẹ pe awọn eeyan ati ileeṣẹ
kọọkan ti a mọ, ti wọn si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, gbogbo wọn ni wọn si ri ọjọ
iwaju rere ninu agbekalẹ wa. Ẹ jẹ ki n dupẹ lọwọ Sir Kessington
Adebutu, alaṣẹ Premier Lotto; awọn alaṣẹ ileeṣẹ Bet9ja; Manal Nigeria Limited to wa ni
Arepo; Ọtunba Ṣubomi
Balogun; Nigerian Breweries; Airtel; Tunde Lẹmọ; Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo; atawọn igbimọ lọba-lọba kaakiri ipinlẹ Ogun ni wọn ṣe gudugudu meje ati
yaya mẹfa.
No comments:
Post a Comment