ẸGBẸ FIBAN IPINLẸ OGUN ṢE IRANTI GBENGA ADEBOYE ATI TỌBA ỌPALẸYẸ LARA-ỌTỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 30, 2019

ẸGBẸ FIBAN IPINLẸ OGUN ṢE IRANTI GBENGA ADEBOYE ATI TỌBA ỌPALẸYẸ LARA-ỌTỌ

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan ni eto naa ṣi n lọ lọwọ ni gbọngan ayẹyẹ tawọn oniroyin, iyẹn NUJ to wa ni Oke-Ilewo niluu Abẹokuta nibi ti ẹgbẹ sọrọsọrọ ipinlẹ Ogun labẹ alaga wọn, Kọmureedi Iyanda Olufẹmi Omilani ti n ṣe iranti awọn akọni meji nni, Oloogbe Gbenga Adeboye ati Oloogbe Atọbatẹlẹ Ọpalẹyẹ.

Ohun tawọn kan maa n sọ ni pe, ọmọ ẹgbẹ sọrọsọrọ to da duro, iyẹn Independent Broadcasters' Association of Nigeria (FIBAN) ti ko ba ṣe iranti awọn akọni meji yi, ọmọ ale ni, tori pe awọn Oloogbe yi ni wọn sọ iṣẹ naa di irọrun fawọn to wa nidi ẹ lonii.

Nigba aye Gbenga Adeboye, ko si oriṣi eto ti ko le ṣe, bo ṣe n ṣe ti idaraya, bẹẹ lo n ṣe amuludun, to si tun nn ṣe iriri aye. Yatọ si eyi, akaikatan awo orin ni Oloogbe Gbenga Adeboye ti ṣe jade, to si tun ṣe sinima rẹpẹtẹ.

Bẹẹ naa ni Oloogb Tọba Ọpalẹyẹ ko ipa ribiribi ninu ẹgbẹ naa ko to o jade laye lọdun mẹtala sẹyin.

Koko pataki idanilẹkọọ ti wọn ṣe lati fi sọri iranti awọn akọni meji naa lọdun yi ni: Gbigbe Ohun Safẹfẹ: Ana, Onii ati Ọla ni Dọkitọ Goke Rauf to jẹ alakoso ẹka iṣẹ igbohunsafẹfẹ nileewe Gbogboniṣe ti Moshood Abiọla fẹẹ sọrọ le lori.

Lara awọn agbaagba nidi iṣẹ igbohunsafẹfẹ ni: Aarẹ ẹgbẹ naa, Desmond Abiọdun Nwachukwu; Alakoso ileeṣẹ redio ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Busayọ Ọlaifa; Abiọdun Bello ti ileeṣẹ OGBC; Aṣamu Akinrinde; Ibiyẹmi Ajadi; Gbenga Ọladunni, Imalian Man; Akinyẹmi Ọlatoye, Alawiye; Hellen Njoku; Abiọdun Adeoye, Afẹfẹ Ọrọ; Ẹrẹkẹ Ni Ṣọọbu; Gbenga Goke Fadiran; Aderoju Ogundiran; Ayọbami Adelani, Ọba Pedepede; Baakini; Van Garuba; Ayinla Ẹgba; Musiliu Sani, Mista Bẹbẹ.

Awọn min in ni: Pasito Ṣọla Makinde; Samson Akindele to jẹ ọga agba ileeṣẹ redio Fresh; Sẹnetọ Makinde Fasunle; Ọlayẹmi Adewunmi, Owurubutu; Mayọwa Sani Arẹwa, Abajigin, Ṣẹgun Laṣilẹ atawọn min in.

Diẹ lara awọn fọto eto naa to n lọ lọwọ:



















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI