DANDAN NI KI GBOGBO AWỌN TO N PE ORUKỌ JESU ṢAYẸYẸ AJINDẸ – BIṢỌỌBU OKUNLỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 22, 2019

DANDAN NI KI GBOGBO AWỌN TO N PE ORUKỌ JESU ṢAYẸYẸ AJINDẸ – BIṢỌỌBU OKUNLỌLA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta: Bi awọn Kristẹni kaakiri agbaye ṣe n ṣayẹyẹ Ajinde Jẹsu lonii, ọkan lara awọn Wolii ti Ọlọrun n gba fun lasiko yi, Biṣọọbu Jeremiah Tunji Okunlọla ti sọ pe dandan ni ki gbogbo awọn ti wọn n pe orukọ Jesu ṣayẹyẹ Ajinde to n lọ lọwọ yi, nitori pe Ajinde naa ni nikan ni pẹpẹ ti wọn fi wa laaye.

Lọjọ Sande ana ni Biṣọọbu Jeremiah Okunlọla tawọn eeyan tun n pe ni Baba Ori-Oke ati Baba Ire Owurọ b’AWIKONKO sọrọ naa niluu Abẹokuta laipẹ yi.

Wolii to kun fun agbara Ẹmi Mimọ naa sọ pe “Bi ayẹyẹ kan ba wa to yẹ ki Kristẹni maa ranti, Ajinde lo yẹ ko jẹ nitori pe oun ni nnkan ti Kristẹẹni fẹyinti. Bibeli sọ pe bi ko ba jinde, igbagbọ wa ati ajinde wa, asan ni. Ajinde Jesu ni pẹpẹ ti awọn Kristẹẹni fi wa laaye, ati pe bi ko ba si ajinde, ko si nnkan to n jẹ Kristẹẹni, ko si nnkan to n jẹ igbagfbọ, ko le si ọrun, ko le si aaye lẹyin iku, gbogbo nnkan yoo kan dabi ojiji ero ati igbagbọ ni.

“Mi o ro pe ijọ kan wa ti ki i ṣe iranti ayẹyẹ Ajinde Jesu, o kan jẹ ọna ti onikaluku n gba ṣe e lo yatọ sira wọn. Bi apẹẹrẹ, ninu ijọ ti wa, a bẹrẹ pẹlu aawẹ ati adura ogoji ọjọ, lẹyin la ṣe Fraide Rere ati sande Rere, ti a si maa ṣe eto min in lonii Monde Ajinde. Ninu ijọ min in, wọn ki i ṣe awọn nnkan wọnyii, ṣugbọn wọn maa n lọ si ipagọ.

“bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yi, awọn ijọ Deeper Life kaakiri agbaye wa ni ipagọ lọwọlọwọ,  ọna min in ti wọn tun n gba ṣe e niyẹn. Gbogbo ijọ onigbagbọ lo gbọdọ ṣe iranti Ajinde nitori pe oun ni idi pataki ki a fi jẹ Kristẹẹni. Ki a lọ si Galili wa lara ọna ti a tun fi n ṣe ayẹyẹ naa. Nnkan ti Jesu ṣe gẹgẹ bi bibeli ṣe fi ye wa la n gbiyanju lati mu wa si ojuṣe fun awọn iran kekeeke to n bọ lati mọ.

“Jesu sọ fun awọn to lọọ pade ẹ pe ki wọn pade oun ni Galili, nigba to si de bẹ, o ba wọn jẹun papọ, o si ba wọn mu, awọn nnkan wọnyii la n mu wa si ojuṣe fawọn iran tuntun to ṣẹsẹ n de, fawọn naa lati maa tẹsiwaju ẹ lọjọ iwaju.”

Pupọ ninu awọn eeyan ti wọn mọ Biṣọọbu Jeremiah Okunlọla, Baba Ire Owurọ ni wọn tun n pe Baba naa ni Wolii, nigba to si n dahun ibeere to fi ri bẹẹ, O sọ pe “Orukọ mi ni Jeremiah Okunlọla, inu ijọ ti mo wa yi, wọn ni awọn ọna ti wọn fi n pe awọn iranṣẹ Ọlọrun wọn. Lati ori Diakoni la ti bẹrẹ, titi de Alagba, iyẹn Priest, latibẹ la ti de ori Kanọọnu (Canon), to fi de Diakoni Agba (Arch Deacon), ka to tun lọ si Fẹnẹrebu (Venerable).

“Bi o ba ni anfaani lati gba aami ororo nla, o maa di Biṣọọbu, ti Ọlọrun si ti fun mi oore-ọfẹ lati la awọn ipele yi kọja, ati pe lonii, ọlọrun ti sọ mi di Biṣọọbu, iyẹn gẹgẹ bi ijọ ti mo wa ṣe faaye gba a. Ati pe gẹgẹ bi ọfiisi ti mo dimu ninu ijọ African Church yi, ọfiisi Biṣọọbu ni. Bi ẹnikẹni ba pe mi ni Wolii, boya nnkan ti wọn ro nipa mi niyẹn, tabi ko jẹ pe oju ti wọn fi n wo mi niyẹn.

“Gegẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju, orukọ mi ni Jeremiah Okunlọla. Ninu ilana African Church, wọn n pe mi ni Rt-Reverend tabi Biṣọọbu. Ẹnikẹni lo le pe mi lorukọ boo ba ṣe ri mi. Bi ẹ ba ri mi gẹgẹ bi Wolii, ẹ le pe mi ni Wolii; Bi ẹ ba ri mi gẹgẹ bi Ajihinrere, ẹ le pe mi bẹẹ; bi ẹ ba si ri mi gẹgẹ bi i Rẹfurẹndi, ko si nnkan to buru nibẹ, ṣugbọn nnkan ti mo mọ ni pe Jeremiah Okunlọla lorukọ mi.

“Bo tilẹ jẹ pe ninu ijọ African Church, ko si ọfiisi fun Wolii tawọn oloyinbo n pe ni Prophet, ṣugbọn wọn faaye gba a lọna to ba ilana Kristẹẹni mu.”

Siwaju si i nipa boya o ṣee sẹ kawon Kristẹẹni darpọ mọ oṣelu orileede Naijiria lai mu ọkan mọ ekeji, Baba Ori Oke jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to buru nibi pe ki Kristẹni darapọ mọ oṣelu, ati pe o ṣee ṣe ki Kristẹni darapọ mọ oṣelu lai mu ọkan mọ ekeji.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Bẹẹni, o ṣee ṣe, lasiko ta a wa yi, a ti n ri awọn Kritẹẹni rere nidi oṣelu, eyi lo si n jẹ ka maa ri ipa ayipada rere lawujọ wa, paapaa nidi oṣelu. Mo maa n sọ fawọn eeyan pe bi wọn ba yan mi sipo oṣelu kan, ko si nkan to le mu ki n de bẹ, ki n wa a gbagbe ibi ti mo ti n bọ, tabi pe ki n pa Jesu ti mo n sin ti, tabi pe ki n gbe igbagbọ mi ninu Jesu ti sẹgbẹ kan, ko le ṣee ṣe.

“Nnkan to le buru ju nibẹ ni pe wọn le ma fun mi ni ipo to ṣe, ṣugbọn mo maa ri i daju pe pe ibikibi ti wọn ba fi mi si, mo maa lo o fun ogo ọlọrun. Yatọ si eyi, ọpọ awọn Kristẹẹni ni wọn ti wa ninu oṣelu lasiko Mo si fẹẹ rọ awọn Kristẹẹni kaakiri pe ki wọn ma ṣe fi oṣelu silẹ fawọn alaigbagbọ. Ẹnikan ti sọ ọ ri pe bi a ba fi ijọba silẹ fawọn alaigbagbọ, wọn maa ṣe ofin aigbagbọ fawọn onigbagbọ, ti wọn si gbọdọ mu lo. Nitori naa, onigbagbọ ko gbọdọ sa sẹyin nidi oṣelu.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI