Atẹjade kan lati ọwọ Tunde Rahman
to jẹ oludamọran Tinubu lori ọrọ iroyin ni ko si ootọ kankan ninu iroyin kan to
jade wi pe Tinubu gbe igbesẹ naa lori bi APC ko ṣe ṣe daadaa ninu idibo sile
aṣofin agba ati ti Aarẹ, eyi to kọja lo.
Abiọla Ajimọbi nikan ni oludije
fun ipo sẹnetọ ninu ẹgbẹ APC to fidirẹmi nipinlẹ Ọyọ.
Tinubu ninu ọrọ rẹ sọ pe, ko da, ọrẹ ni oun ati Ajimọbi, ati wi pe idi ti oun fi da si ọrọ APC ni Ọyọ ni lati ri wi pe ẹgbẹ naa
ṣe daradara ninu idibo gomina to n bọ, kii ṣe wipe oun fẹ gba ipo lọwọ rẹ.
Atẹjade naa gbe ori yin fun Ajimọbi.
'O ti ṣe daradara ni Ọyọ ati
wipe ohunkohun ti APC ba ri mu ni ipinlẹ naa, nitori Ajimọbi ni.'
O tun fi han wi pe nitori
igbesẹ ti Tinubu gbe ni Ọyọ lo mu ki ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina ni
ipìnlẹ naa, Alao Akala pada si APC.
Tinubu ni iwe iroyin to gbe
ofege iroyin naa nipa oun ati Ajimọbi jade kan fẹ sọ ọmọ iya meji di ọta ara
wọn ni.
- BBC
- BBC
No comments:
Post a Comment