WỌN FI OYE TUNTUN DA EBUTE ARIYA LỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 30, 2019

WỌN FI OYE TUNTUN DA EBUTE ARIYA LỌLA

Gbogbo eto lo ti pari bayii lati fi aami ẹyẹ da gbajumọ sọrọsọrọ ori tẹlifiṣan nni alatagba nii, Star Time, GoTV ati DSTV, Arabinrin Temitọpẹ Amọkẹade Lawal lọla.

Eto naa ti ileeṣẹ KAYDALLAS MEGA ENTERTAINMENT fẹẹ ṣagbatẹru ẹ lọjọ Sande ọla tii ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn la gbọ pe oye Yeye Amuludun ni wọn fẹẹ fi da a lọla gẹgẹ bi ipa ribiribi to ti ko lagboole Aṣa ati Iṣẹṣe.

Temitọpẹ Lawal t'awọn eeyan tun n pe ni Ebute Ariya gẹgẹ bi eto e to fi n mu gbogbo awọn ayẹyẹ Aṣa larinrin lo mu ki wọn fẹẹ fi oye naa da lọla, ati pe ko sẹni meji to tọ si bi ko se oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI