Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti sọ ọ di mimọ pe afikun idibo Aarẹ
yoo waye lọjọ Abamẹta ọsẹ to n bọ tii ṣe ọjọ kẹsan oṣu kẹta ta a wa yi.
Afikun idibo Aarẹ yoo waye lọjọ kan naa pẹlu idibo gomina
ati tile igbimọ aṣofin ipinlẹ kaakiri orileede yi.
Ọga agba ajọ INEC to n ri sọrọ iroyin ati ilanilọyẹ awọn
oludibo, Festus Okoye ṣalayẹ pe idibo Aarẹ naa yoo waye nibi gbogbo ti ajọ INEC
ti wọgile ibo Aarẹ lọjọ Satide ọsẹ to kọ ja.
O fikun ọrọ rẹ pe igbesẹ naa waye nibi ipade awọn ọga
INEC ti ipinlẹ kọọkan l'Abuja.
Ajọ INEC ko le ran awọn oṣisẹ rẹ lọ si awọn ibudo idibo
kan nitori rukerudo to bẹ silẹ lawọn agbegbe ọhun.
- BBC
No comments:
Post a Comment