WAHALA DE L'EKITI, IJỌBA ṢETAN LATI MAA Ṣ'AYẸWO ỌPỌLỌ F'AWỌN TO BA N FIPA BA EEYAN SUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 18, 2019

WAHALA DE L'EKITI, IJỌBA ṢETAN LATI MAA Ṣ'AYẸWO ỌPỌLỌ F'AWỌN TO BA N FIPA BA EEYAN SUN


Beeyan ba wo bi iwa ọdaran, paapaa iwa ifipabanilopọ ṣe n fojoojumọ peleke sii, a fi kijọba tete gbe igbesẹ lee lori ko too too pẹ ju.

Lọjọ Aje Mọnde oni nijọba ipinlẹ Ekiti gbe aṣẹ nla kan sita pe awọn tọwọ ba tẹ pe wọn fipa ba eeyan sun, yala ọmọde ni wọn fipa ba sun ni, tabi agbalagba, ki wọn too gbe ẹni naa lọ sile ẹjọ, wọn yoo kọkọ lọọ ṣe ayẹwo ọpọlọ fun un.

Kọmiṣana fun oro eto idajọ nipinlẹ Ekiti, Onidajọ Ọlawale Fapohunda lo fidi ọrọ naa mulẹ lasiko to n b'awọn akọroyin niluu Ado-Ekiti.

O ni kii ṣe pe awọn yoo ṣ'ayẹwo ọpọlọ fun iru ẹni bẹẹ lasan, awọn yoo tun pe aworan pẹlu orukọ rẹ gadagba sori ayelujara fun gbogbo agbaye lati rii, ki wọn ma si le ba a dowopọ.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe ko nii si idalare tabi oju aanu gomina fun ẹni ti ọwọ palaba rẹ ba segi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI