ṢANGBA FỌ: ỌWỌ EFCC TẸ OLUDIJE SIPO ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ OGUN PẸLU OBITIBITI OWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 9, 2019

ṢANGBA FỌ: ỌWỌ EFCC TẸ OLUDIJE SIPO ILE IGBIMỌ AṢOFIN IPINLẸ OGUN PẸLU OBITIBITI OWO

Ṣe lọpọ awọn oludibo ni wọọdu keje to wa lagbegbe Ijaye niluu Abẹokuta la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko fẹẹ le pa a de nigba taṣiri ọkan lara awọn oludije sipo ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Ṣotayọ Ọlatayọ Johnson pẹlu obitibiti owo to fẹẹ fi ra ibo.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ni pe ni nnkan bi aago kan ọsan oni lọwọ tẹ oludije Ṣotayọ Ọlatayọ lasiko to n ko owo naa jade ninu mọto ẹ, to si fẹẹ fawọn eeyan lati dibo foun ati oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa.

Ṣotayọ Ọlatayọ Johnson n dibo sipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement, APM lẹkun Abẹokuta South 1.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI