PASITỌ FUN ỌMỌDUN MẸTADINLOGUN LOYUN, LO BA TUN ṢẸ OYUN NAA FUN UN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 23, 2019

PASITỌ FUN ỌMỌDUN MẸTADINLOGUN LOYUN, LO BA TUN ṢẸ OYUN NAA FUN UN

Ika abamọ ni wọn ni oludasilẹ ṣọọṣi Gloryland nipinlẹ Ẹdo, Ekene Samuel ti wọn lo n f'orukọ Ọlọrun boju, ṣugbọn to jẹ pe iranṣẹ eṣu paraku ni mu sẹnu lọgba ọlọpaa to ti n gbatẹgun bayii.

Ọmọdun mẹtadinlogun (17) kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Miracle la gbọ pe Samuel fun loyun, to si n gbiyanju lati ṣe oyun yi f'ọmọ naa, ko too di pe ọrọ naa yiwọ mọ wọn lọwọ.

AWIKONKO gbọ pe yatọ si pe Samuel n f'orukọ Jesu boju, o tun n ṣiṣẹ iṣegun fawọn eeyan kaakiri.

Oṣu kẹjọ ọdun to kọja la gbọ pe Samuel bẹrẹ sii ko ibasun fun Miracle ninu ṣọọṣi Gloryland to da silẹ, ojiji ni wọn ni Miracle loyun mọn ọn lọwọ.

Ki aṣiri ma ba a tu lo mu ki Samuel pe ọkan lara awọn iya ijọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Happy Johnson lati lọọ ṣe oyun fun Miracle lọsibitu, idi ni yii ti wọn ni Happy fi muu lọ si ọsibitu Gracevill to wa lagbegbe Ewah Road.

Ṣe ni wọn lọrọ naa yiwọ mọ Dọkita to yọ oyun naa lọwọ, nitori ta a gbọ pe ọmọ ti ku sinu Miracle. Eyi ni wọn loo fa a ti wọn fi daa duro lati tọju ẹ daadaa.

Nigba t'awọn mọlẹbi Miracle ko ri ọmọ wọn lo mu ki ẹgbọn Miracle, Henry Aikhuaman gba teṣan ọlọpaa lọọ f'ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ki wọn to lọọ gbe Samuel nile.

Lẹyin iwadii ni wọn pada ri Miracle lori bẹẹdi ti wọn ti n tọju ẹ. Ko too di pe Samuel pada jẹwọ pe oun ti kọkọ fun Miracle loogun lati fi ṣẹyun, eyi to fa aisan sii lara.

Ninu iwadii siwaju sii lawọn ọlọpaa tun ti ba oriṣiriṣi oogun ninu ṣọọṣi ẹ, eyi ti wọn lo fi n de awọn eeyan sinu igbekun.

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti sọ pe afi ki Samuel foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI