Oludije sipo Gomina labẹ asia
ẹgbẹ oṣelu New Progressive Movement (NPM) nipinlẹ Ọyọ, colonel Feyiṣayọ Ladoye
ti kese sita gbangba pe oun ko dije dupo naa mọ, ati pe oun yoo ṣagbatẹru adije
sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọgbẹni Ṣeyi
Makinde.
Colonel Ladoye, to fi apa kan tan mọ ilu
Ogbomọṣọ naa sọ pe ko si nnkan meji to jẹ koun fa sẹyin lati sọ pe oun ko dupo
naa mọ, bi ko ṣe pe lati fun oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni anfaani
lati de ipo naa, ati pe lati jẹ kawọn eeyan gbaruku ti rẹpẹtẹ.
Nigba to n gbawọn ọmọ ẹgbẹ
oṣelu NPM naa lamọnran pe ki wọn dibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP lọjọ Satide Abamẹta to
n bọ yi nitori pe bawọn ba yan Ṣeyi makinde sipo naa, yoo ṣe daadaa ju ẹgbẹ
oṣelu APC to ti ja wọn kulẹ lọdun mẹjọ lọ.
O ni boun ko ba fipo naa silẹ
fun Ṣeyi makinde, bi ẹni to kan fẹẹ ba ibo ọjọ naa jẹ fun ẹgbẹ PDP ni, ati pe
ẹgbẹ APC yoo lanfaani lati rọwọ, ati pe Ṣeyi Makinde mọ ọna abayọ si iṣoro to n
koju ileewe giga gbogboniṣe ti LAUTECH.
Nigba to n rawọ ẹbẹ sawọn ẹgbẹ
oṣelu kekeeke to ku pe ki wọn ṣagbatẹru ẹgbẹ oṣelu PDP, o ni ilu Ogbomọṣọ nikan
lawọn oludije naa n wo lati ri ibo to pọ ju nipinlẹ Ọyọ.
No comments:
Post a Comment