ỌBASANJỌ LO MU AYIPADA RERE DE BA OṢELU NAIJIRIA - AARẸ BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 6, 2019

ỌBASANJỌ LO MU AYIPADA RERE DE BA OṢELU NAIJIRIA - AARẸ BUHARI

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe àfiwé ààrẹ àná, Olusegun Obasanjo gẹ́gẹ́ bíi olùfarajì tòótọ fún ìdàgbàsóke Nàìjíríà tó sì yẹ láti máà gbóríyìn fún.

Buhari ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ribiribi ti Ọbasanjọ ti gbése lo mu ki ìjọba awa ara wa àti ìsọ̀kàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kó gbòòrò si.

Nínú àtẹjáde kan ti Garba Sheu, to jẹ oluranlọwọ pataki fún ààrẹ kọ láti fi ki ààrẹ ànà Olusegun Obasanjo fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹrìnlélọgọrin rẹ, ni Buhari ti woye ọrọ yii.

Ààrẹ Buhari ni "bó tilẹ jẹ pé èmi àti Obasanjo ò jọ dúró si ibi kan náà lórí ọ̀rọ̀ ètò òṣèlú, síbẹ̀ mi ò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ múu nítori gbogbo àwọn iranwọ rẹ̀ lórí ìdàgbàsókè Nàìjíríà."

O ní, "àwọn àlàyé ti Oloye Olusegun ṣe nipa ara rẹ̀ àti àwọn amuyẹ adarí to ni, máà ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni ìwúrí. "

Gẹ́gẹ́ bi Buhari ṣe sọ, "ọ̀nà ti Nàìjíríà gba láti kúrò nínú ìjọba ológun sí ti alágbáda lọdún 1979, kò ṣẹ̀yìn àwọn iṣẹ́ribiribi ti Obasanjo gbé se fun ìdagbasoke àpapọ orilẹ̀-èdè Nàijiríà".

Ààrẹ Buhari ni, "Bí ó ṣe wá ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbì ọdún méjìlélọ́gọ́rin, mo gbàdura fún àlékun àláfíà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ nínú sínsin Ọlọrun àti ènìyàn."

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI