O TAN: NITORI GBENGA DANIEL, ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR LOUN YOO GBE ẸGBẸ OṢELU APC, GOMINA AMOSUN ATI ỌṢỌBA LỌ SILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 19, 2019

O TAN: NITORI GBENGA DANIEL, ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR LOUN YOO GBE ẸGBẸ OṢELU APC, GOMINA AMOSUN ATI ỌṢỌBA LỌ SILE ẸJỌ

Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayọmi Arabambi ti dunkooko mọ egbe oṣelu All Progressives Congress, APC, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ati Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun pe oun yoo gbe wọn lọ sile ẹjọ bi wọn ba fi le gba Gomina ana nipinlẹ naa, Otunba Gbenga Daniel laaye ninu ẹgbẹ naa.

Kọmureedi Abayọmi Arabambi to jẹ alaga fun gbogbo awon alaga ẹgbẹ oṣelu patapata nipinlẹ Ogun, iyẹn IPAC lo sọrọ naa laipẹ yi niluu Abẹokuta.

Arabambi to ṣapejuwe Ọtunba Gbenga Daniel gẹgẹ bi alagabagebe eeyan, ati igi wọrọkọ to da ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun ru nigba to fi jẹ Gomina ipinlẹ Ogun, to si jẹ pe wahala naa ni ko tii tan nilẹ bayii.

O ni Ọtunba Gbenga Daniel tun ti wa loju ọna lati da ẹgbẹ oṣelu APC ru gẹgẹ bo ṣe ṣe ni PDP, nitori naa gbogbo nnkan ti yoo ba gba loun yoo ṣe lati rii pe wọn ko faaye gba a.

Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ to koja yi ni Otunba Gbenga Daniel loun yọwọ kuro ninu oṣelu, lati gbajumọ ajọ alaanu toun da silẹ, eyi ti wọn lawọn ọmọ ẹyin ko gba fun un.

Awon ọmọ ẹyin OGD ni wọn sọ kaka ki ko fawọn silẹ ninu ẹgbẹ naa, ko kuku ko awọn lọọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC, toun naa si sọ pe oun yoo wa nnkan ṣe sii.

Arabambi sọ pe ayafi ti oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar ba loun ko nii gbe Aarẹ Buhari lọ sile ẹjọ Tribunal, ko si ki Aarẹ Buhari ku oriire loun yoo too gba pe Gbenga Daniel ṣetan lati fi oṣelu silẹ, ati pe wọn fẹẹ ran an wa dabaru ẹgbẹ oṣelu APC ni.

O ni wipe OGD ki Omoba Dapọ Abiọdun ku oriire, ko tunmọ si pe o fẹran wọn, nitori pe oun gan n'igi lẹyin ọgba to n ti Atiku Abubakar pe ko lọ sile ẹjọ nitori pe Aarẹ Buhari yi ibo funra rẹ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI