Gomina Fayọṣe lasiko to n kọ ọrọ
naa sọ pe iwe ‘otoge’ni wọn ja fun Gomina Amosun to lewaju lati gba ijọba
ipinlẹ Ekiti lọwọ oun fun ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to kọja.
Ninu ọrọ ẹ, o sọ pe “Mo ki
Gomina Ibikunle Amosun ku oriire pe o padanu idibo gomina ti ọmọ oye ẹ,
Adekunle Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM.
“Oun naa ti wa a le darapọ mọ
ẹgbẹ wa, lẹyin to ti fi tipa ṣagbatẹru bi wọn ṣe yi ibo ipinlẹ Ekiti lọdun 2018
pẹlu Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji yi kan naa to jẹ aṣoju ọga INEC fun eto idibo
nipinlẹ mejeeji.
“ YE Ibikunle Amosun, jọwọ
darapọ mọ wa bi a ti n ja ijangbara ipadanu wa nile ẹjọ Tribunal. Laala to lọ
soke, ilẹ lo n padabọ. Ohun to ba lọ, yoo tun pada wa a ni. Iwọ ja Ekiti gba,
wọn ja Ogun gba lọwọ ẹ.
“YE, jọwọ ma ṣe gbagbe lati ki
Ọlọlajulọ Dapọ Abiọdun ku oriire o.
No comments:
Post a Comment