"Kokoro ko je ki a gbadun obi to gbo" l'orin ibanuje t'awọn mọlẹbi gbajumọ Pasitọ nni Ṣẹyẹ Ṣẹnfuye, ati gbogbo awọn ọmọ ṣọọṣi Treasure House of God to wa lagbegbe Agbẹlọba niluu Abẹokuta n kọ lasiko ta a wa yi latari bi wọn se padanu iyawo Oludasilẹ ṣọọṣi naa, Arabinrin Oluyẹmisi Ṣẹnfuye.
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, irọlẹ ọjọ Mọnde ijẹta lobinrin to fi ara rẹ silẹ fun iṣẹ Oluwa naa dagbere faye lẹyin aisan rampẹ ti wọn loo da a dubulẹ.
Ninu atẹjade ti oludamọran Pasitọ Ṣẹnfuye lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Niyi Adeloye fi ranṣẹ si AWIKONKO ni nnkan aago mẹta aabọ ọsan oni lo ti jẹ ko di mimọ pe iku oloogbe naa bani ninu jẹ pupọ.
Bo tilẹ jẹ pe Ọgbẹni Niyi Adeloye ko ṣalaye bi eto isinku yoo ṣe lọ si, sibẹ o jẹ ko ye wa pe ẹlẹyinju aanu, oniwa irẹlẹ lobinrin naa ko too ku.
No comments:
Post a Comment