Ko daa, Iroyin kan ti a ko le
fidi rẹ mulẹ bayii sọ pe eeyan mẹta lo ti ta teru nipa nigba ti ọpọlọpọ awọn
eeyan si farapa yanna-yanna.
Lakọ-lakọ ni iro ibon n dun, ti
ko si si ifọkanbalẹ fun ẹnikẹni. Idajọ kan la gbọ pe awọn eeyan ilu Yakoyo gba
nile ẹjọ giga ilu Ifẹ laarin ọsẹ to kọja yii.
Idajọ yi la gbọ pe o fun wọn laṣẹ
lati lọọ gba awọn ilẹ wọn tawọn eeyan ilu Moro ti gbẹsẹ le.
A gbọ pe wọn lọ ba DPO ileeṣẹ ọlọpaa
ilu Moro lati fun wọn llawọn ọlọpaa lati le mu idajọ kọọtu naa ṣẹ, ṣugbọn iyẹn
sọ fun wọn pe Kọmiṣanna ọlọpaa lo lagbara lati ṣe bẹẹ.
Laarọ ọjọ Satide to kọja yi ni
wọn lawọn eeyan ilu Yakoyo bọ sita pẹlu atilẹyin Baba oloṣelu kan niluu naa,
gẹgẹ bi ahesọ ti a gbọ. Baba naa taa forukọ bo laṣiri yii lo fun won lawọn ṣọja
kan to n tẹle wọn kaakiri awọn agbegbe ti ilu Moro ti tasẹ agẹẹrẹ wọnu ile wọn.
Bi wọn ṣe debẹ la gbọ pe awọn
eeyan ilu Moro pe wọn nija lori nnkan ti wọn n ṣe, ta a si gbọ pe eyi lo bi ọkan
lara awọn ṣọja naa ninu, to si ṣina ibọn bolẹ, bayii ni wahala bẹrẹ latigba
naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun
fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn wọn ko le sọ boya ẹnikẹni gbẹmi mi in ninu iṣẹlẹ
naa.
No comments:
Post a Comment