Pupọ ninu awọn
to wa ninu gbagede Aṣa ati Iṣe, iyẹn Cultural Centre to wa ni Kutọ niluu Abẹokuta,
ti wọn ri bi Yẹmi Adegunju ṣe diju mọri, to n sọ pe afi koun gba owo oun ni wọn
fẹẹ le maa ba a sunkun pẹlu bo ṣe n ṣe lọjọ naa.
Sinima lọpọ
awọn to wa nibẹ lọjọ Wẹside ọsẹ to lọ lọhun, nibi ti oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ
asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Abudukabir Adekunle Akinlade ti pe awọn amuludun
kaakiri ipinlẹ naa, lati ba wọn ṣepade pọ kọkọ ro pe wọn ya lasiko naa, afigba
tawọn eeyan ri i pe wọn ko fi ọrọ naa ṣe sinima rara.
Ko ju bi i ọgbọN
iṣeju lẹyin ti wọn pari ipade naa, tawọn eeyan bọ sita ni Adegunju naa bọ sita
to si ri ọmọbinrin kan to n ta kokoro. Bo ṣe ri ọmọ naa lo sare pe e lati ra
kokoro, to si tun bẹ ọmọbinrin naa pe ko ba oun ra omi inu ike.
Ọgọrun kan
(100) la gbọ pe Yẹmi Adegunju fun un pe ko fi ra omi, ti wọn si ni ọmọ naa ko
pada wa latigba naa. Lẹyin bi wakati kan aabọ la gbọ pe awọn mejeeji tun to o
pada foju kan ara wọn, bi Adegunju ṣe ri ọmọ naa lọọkan lo ti sare dide lati
gba oju ẹ.
“Iwọ ọmọ
buruku yi, ki ṣe o ro pe mi o ni pada ri ẹ ni, ki lo de to o gbe owo mi salọ,
ti mo si sọ fun ẹ pe orungbẹ n gbẹ mi, pe ko o ba mi ra omi wa. Ba mi gbe owo
mi, mi o ra mọ.”
Ere lawọn
eeyan kọkọ pe e, oju ti ọkunrin naa gbe lo jẹ ki wọn mọ pe inu bi gidigidi, ati
pe awọn oniroyin to wa nitosi ni ko jẹ ko lu ọmọ naa, awọn ti wọn wa nitosi ni
wọn ba ọmọ naa bẹbẹ pe ko sare lọọ ra omi naa wa.
Bọmọ naa ṣe
fẹẹ lọọ ra omi yi ni Yẹmi Adegunju ni oun ko nii gba ko lọ, ayafi to ba sọ ẹru ọja
ẹ kalẹ, nitori pe o ṣee ṣe ko tun gbe owo naa salọ patapata. Ẹrin lawọn to wa
nibẹ bu si.
Pupọ ninu awọn to wa nibẹ ni wọn lanu
gbaga, ti wọn ko fẹ ẹ le pa a de pẹlu bi wọn ṣe sọ pe owo ka ọkunrin
gbajumọ taita naa lara to bẹẹ.
Ohun tawọn kan ti ẹ n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe owo ti
ko fi bẹẹ si lowo ẹ mọ daadaa ni
lo jẹ ko ṣe bẹẹ, tawọn min in si
n sọ pe eelo ni ọgọrun naira ti
ko le fun eeyan, ko si gbagbe.
No comments:
Post a Comment