Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii,
afaimọ ki Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ma padanu ipo sẹnetọ ti wọn dibo
yan-an wọle lọsẹ to kọja yi, nitori bi igbimọ ẹgbẹ naa, iyẹn National Working
Committee fẹgbẹ oṣelu APC niluu Abuja ṣe kede pe awọn da ọkunrin naa duro ninu
ẹgbẹ naa pẹlu erongba lati lee danu ninu ẹgbẹ naa patapata.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni
wọn ti ṣalaye pe awọn da Gomina naa ati akẹgbẹ ẹ nipinlẹ Imo, iyẹn Gomina
Okorocha duro lori iwa agabangebe ti wọn n hu ninu ẹgbẹ naa lati ọdun to kọja.
Bẹẹ ni wọn tun gbe e siwaju
awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa pẹlu amọnran lati le awọn mejeeji danu, nitori gbogbo iwa
ko kan mi tawọn mejeeji n hu ko ba ofin ẹgbẹ mu, to si jẹ pe kaka ki wọn jawọ,
ṣe lo tun n peleke sii fun wọn ni.
Latigba ti ẹgbẹ lapapọ si kede
idaduro Gomina Amosun ni ẹgbẹ APC tipinlẹ Ogun ti sọrọ sita pe idaduro kọ nikan
lawọn n fẹẹ, ki wọn le ọkunrin naa danu ninu ẹgbẹ APC ni yoo bojumu.
Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni
Tunde Ọladunjoye, to jẹ akọwe olupolongo ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Fraide ana an, lo
ti ṣalaye pe igbesẹ ti National Working Committee naa gbe lo yẹ ko ti waye tipẹ.
Atẹjade naa tun ka bayii
‘Gbogbo igbesẹ ti Gomina Amosun gbe lo jẹ ti alaimoore, to si tun jẹ agabangebe
ẹgbẹ, awa pe igbimọ NWC ẹgbẹ naa lati tẹ siwaju ninu igbesẹ wọn, ki wọn si lee
danu patapata, eyi ni yoo jẹ ẹkọ fun un lọjọ iwaju atawọn to ba tun fẹẹ ṣe
awokọṣe ẹ.
Ṣugbọn bi nnkan ṣe n tun ti wa
n lọ, bi ẹgbẹ ba fi le le Amosun danu ninu ẹgbẹ naa, o ṣe e ṣe ki wọn gba
tikẹẹti to fi wọle fun ipo sẹnetọ lọsẹ to kọja, ki wọn si gbe e fun elomin in.
A tiẹ tun gbọ pe wọn ti ni ki
Sẹnetọ Lanre Tẹjuoṣo to ṣi wa nipo naa lọwọlọwọ, ko maa mura silẹ. Amọ ṣa, ibi
ti ọrọ ere ori itage tẹgbẹ oṣelu APC ṣe n lọwọ yoo fidi si ko tii sẹni to le sọ.
- BO ṢE RI
No comments:
Post a Comment