NITORI AKẸKỌỌ TI WỌN LE LỌ SILE LATARI OWO ILEEWE T'AWỌN OBI RẸ KO RI SAN, IJỌBA LE ỌGA ILEEWE DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 18, 2019

NITORI AKẸKỌỌ TI WỌN LE LỌ SILE LATARI OWO ILEEWE T'AWỌN OBI RẸ KO RI SAN, IJỌBA LE ỌGA ILEEWE DANU

Laipe yi ni fọnran akẹkọọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Success Adegor jade sita pẹlu bo ṣe n binu pe wọn le oun kuro nileewe nitori owo ileewe t'awọn obi rẹ ko ri san.

Ileewe alakọọbẹrẹ ti Okotie-Eboh to wa niluu Sapẹlẹ, ipinle Delta la gbọ pe wọn ti le Success, to si n binu pe ṣe lo yẹ ki wọn lu oun dipo ki wọn le oun pada sile.

Fọnran yi ni won loo tẹ awọn adari eto ẹkọ nipinlẹ naa lọwọ, to si mu ki Kọmiṣana feto feto eko, Amofin Chiedu Ebie gbera lọ sibẹ, to si da oga ile ẹkọ naa, Arabinrin Vero Igbigwe duro.

AWIKONKO gbọ pe Arabinrin Igbigwe ko ri ọrọ gidi kan sọ nípa owo idanwo ti wọn tori ẹ le Success pada sile, eyi gan an ni wọn loo mu ki wọn sọ pe a fi koun naa ṣi lọọ jokoo sile fungba diẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI