Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti ni, idi ti oun fi n tako Aarẹ Buhari ni wi pe isejọba tiwantiwa faaye gba ki eniyan o sọrọ nipa ijọba to wa lode.
Aarẹ Obasanjo ni asiko to n ṣe ayẹyẹ ọdun kejilelogun ni ilu abeokuta sọ wi pe ko si ija laaarin oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari.
O ni isẹ ilu kii se ohun ti eniyan fi n ṣe ibatan, amọ o nii ṣe pẹlu titako igbesẹ ijọba ti ko ba ba awọn eniyan lara mu.
Ni ọpọ igba, Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ma n bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.
- BBC
No comments:
Post a Comment