LASIKO TI IDIBO N LỌ LỌWỌ: ỌNỌREBU AKINLADE TUN GBE IPOLONGO DE ILE IDIBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 9, 2019

LASIKO TI IDIBO N LỌ LỌWỌ: ỌNỌREBU AKINLADE TUN GBE IPOLONGO DE ILE IDIBO

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi idibo ṣe n lọ lọwọ kaakiri orileede Naijiria, Oludije sipo Gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Abdulkabir Akinlade ti gbe ipolongo lọ dibo ni wọọdu ẹ.

Ni nnkan bi aago mẹwaa ku iseju mẹwa ni Ọnọrebu Akinlade gba iwe idibo lọwọ àwọn aṣoju ajo INEC ni Wọọdu keta, ile idibo kejilelogun (Ward 3, Unit 22) ni lagbegbe Agọṣaṣa, niluu Ipokia.

AWIKONKO gbọ pe bi Ọnọrebu Akinlade ṣe de ibi to ti fẹẹ dibo naa lawon eeyan ti bẹrẹ sii kii ni mẹsan mẹwa, toun naa sì n rẹrin si wọn, to tun n ju ọwọ soke.

Bo ṣe gba owe idibo naa tan, pelu iyawo ẹ, Arabinrin Chinenye Adeṣẹwa Akinlade ni wọn ba gbe e soke, t'awọn to wa nibẹ si n pariwo ''Triple A".

Ohun tawọn eeyan n so ni pe sẹ ni oludije naa tapa si ofin ajọ INEC pe ẹnikẹni ko gbọdọ polongo lasiko idibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI