INEC KEDE DAPỌ ABIỌDUN GẸGẸ BI GOMINA TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 11, 2019

INEC KEDE DAPỌ ABIỌDUN GẸGẸ BI GOMINA TUNTUN

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Ko too di pe ajọ eleto idibo orileede yi, INEC, ẹka tipinlẹ Ogun kede oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Ọmọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ni oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Allied people’s Movement, Ọnọrebu Adekunle Akinlade ti sọ pe oun ko nii gba esi idibo naa wọle, dipo bẹẹ, ile ẹjọ ni yoo ba wọn da si.

Yatọ si pe Ọnọrebu Akinlade pariwo sita pe oun ko nii gba esi naa nitori pe awuruju pọ nibẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe lawọn agbegbe idibo kan, Ṣarafa Tunji Iṣọla to jẹ adari olupolongo fẹgbẹ oṣelu APM naa fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC pe magomago pọ ninu idibo to kọja lọ naa.

Wọnyi ni bi esi ibo naa ṣe lọ:

Awọn ti wọn forukọ silẹ fun eto idibo (Registered Voters): 2,375,003
Awọn ti wọn forukọ silẹ fun idibo (Accredited Voters): ACCREDITATION: 708,807

Ẹgbẹ oṣelu ati iye ibo ti wọn ni:
A: 1,695
AAC: 1,469
AAP: 746
ACD: 2,629
AD: 1,378
ADC: 110,422
ADP: 9,666
AGA: 813
ANN: 710
ANRP: 958
APC: 241,670
APM: 222,153
ADS: 235
BNPP: 345
C: 81
CAP: 150
DA: 753
DPC: 464
DPP: 732
FRESH: 161
GPN: 242
ID: 159
JMPP: 191
KP: 552
MPN: 628
NCP: 430
PDP: 70,290
PPA: 1,133
PPC: 616
PPN: 1,149
PPP: 671
PT: 365
RPMP: 602
SDP: 1,483
UDP: 384
UPN: 861
UPP: 515
YES: 1,692
YPP: 735
ZLP: 616

Ibo to peregede (Valid Votes): 680,947
Ibo to bajẹ (Void Votes): 20,969
Apapọ ibo (Total Votes Cast): 701,916

Aala to wa laarin ẹni to gbegba oroke ati ẹni to ṣe ipo keji (Winning Margin): 19,517:
Ibo ti won fagile: 7,100

Ọjọgbọn Idowu Ọlayinka, to jẹ oludari ibo nipinlẹ Ogun sọ pe Ọmọba Dapọ Abiọdun yege latari bo ṣe bọ lọwọ gbogbo

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI