ILU EKO PA LỌLỌ NITORI IKU OLUMẸGBỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 25, 2019

ILU EKO PA LỌLỌ NITORI IKU OLUMẸGBỌN

Ṣe ni gbogbo ilu Eko pa lọlọ nigba tiroyin iku Olumẹgbọn tiluu Eko, Oloye Abdulfatai Adisa Abiọdun jade sita lojiji, to si mi gbogbo igboro titi.

Aarọ ọjọ Sannde to kọja yi la gbọ pe Olumẹgbọn waja, tiroyin naa si tẹ AWIKONKO.

Fawọn ti ko ba mọ Olumẹgbọn, Oloye Abiọdun ni olori awọn Oloye onifila funfun niluu Eko, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) ni ki ọlọjọ too de.

Latigba tiṣẹlẹ yii ti waye lawọn eeyan ti n ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi Oloye to jade laye ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI