IJỌBA IPINLẸ EKO BẸRẸ ILE WIWO L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 15, 2019

IJỌBA IPINLẸ EKO BẸRẸ ILE WIWO L'EKOO

Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe ijọba ipinlẹ Eko ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ti ko duro daada ladugbo ibi ti ile ti wo pa eeyan to to mejidinlogun.

Aworan Ile ti ijọba fẹ wo ni Lagos Island
Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, ile mọkandinlogun ni yoo fara gba ninu igbesẹ yi lara awọn ile ogoje ti wọn ti fagile pe awọn yoo wo.

Aworan ọkọ katapila
A gbo bakanna pe wọn ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ni Adugbo Freeman nilu Eko.




Aworan Ile ti ijọba fẹ wo ni Lagos Island
Akọrọyin wa to kalẹ sibi ti wọn ti n wo awọn ile naa ti n fi awọn aworan ile ti wọn yoo wo ranṣẹ si wa

Aworan Ile ti ijọba fẹ wo ni Lagos Island

Lara ohun ti awọn eeyan ke ni gbajare lasiko ti wọn doola ẹmi awọn ti ile wo pa ni Ita faji lọjọru ni pe ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn ile to fẹ wo tan ti awọn eeyan wa ninu wọn.

Ninu fọnran fidio yi ti a ti ba awọn eeyan sọrọ wọn bẹnu atẹ lu bi awọn oṣiṣẹ eleto ile kikọ kan ti ṣe n gba abẹtẹlẹ lọwọ awọn ti wọn ba ti fagile ile wọn fun wiwo.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI