Iwadi ṣi n lọ lọwọ lori ipade
bonkẹlẹ ti wọn ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Dọkitọ Kayọde Fayẹmi ṣe pẹlu Gomina
tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Alao Akala atawọn agbaagba lẹgbẹ oṣelu APC niluu
Ibadan lonii.
Titi dasiko ta a ṣakojọpọ
iroyin yi tan la ko tii le fidi ẹ mulẹ nipa nnkan ti wọn ṣe ipade le lori,
ṣugbọn ta a gbọ pe latari idibo ọjọ Satide Abamẹta ọsẹ to n bọ ni wọn ṣe e le
lori, paapaa bi ẹgbẹ oṣelu APC yoo ṣe rọwọ mu.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yi Ọtunba
Alao-Akala to jẹ oludije sipo Gomina ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADP kede
sita gbangba pe oun ti gbe ipinu lati di Gomina ipinlẹ naa pada ti sẹgbẹ kan,
idi ni pe oun ti gba lati ṣiṣẹ fun adije sipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
AWIKONKO gbọ pe yato si pe
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi lọọ dupẹ gidigidi lọwọ Alao-Akala fun ipinu
ati igbẹsẹ to gbe naa, wọn tun jiroro lori bi wọn yoo ṣe gba ipinlẹ Ọyọ fun
ẹgbẹ wọn, APC lọjọ Satide Abamẹta to n bọ naa.
Lara awọn ti wọn tun wa nibi
ipade naa ni; Ọtunba Ademọla Popoọla to jẹ ọkan lara awọn agba lẹgbẹ oṣelu APC;
Iyawo Alao-Akala, Oloye Arabinrin Kẹmi Alao-Akala, atawọn min in.
No comments:
Post a Comment