Adije sipo Gomina labẹ ẹgbẹ
oṣelu PDP, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde ti pariwo sita pẹlu ẹsun to fi kan ẹgbẹ oṣelu
APC pe wọn n gbiyanju lati da wahala nla silẹ nipinlẹ Ọyọ, paapaa lawọn ilu bii
Ogbomọṣọ, Ibarapa, Oke-Ogun atawọn ilu tẹgbẹ oṣelu PDP ti lẹnu ju wọn lọ fun
idibo ọsẹ to n bọ.
O ni gbogbo igbesẹ tẹgbẹ oṣelu
APC to wa nijọba bayii n gbe ni pe ki wọn da idibo naa ru, ki ajọ eleto idibo,
INEC le sọ pe idibo ko pari, ati pe atundi ibo yoo waye, eyi ti wọn n pe ni
inconclusive, gẹgẹ bo ṣe waye nipinlẹ Ọṣun lọdun to kọja
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ olupolongo
idibo ẹ, Ọmọba Dọtun Oyelade gbe sita lonii, o ni lara awọn ẹgbẹ onimọto ti National
Union of Road Transport Workers (NURTW) ti lọ n halẹ mọ awọn ọlọja atawọn
araalu pẹ dandan ni ki wọn dibo fun ẹgbẹ APC lopin ọsẹ to n bọ naa.
O lawọn agbegbe bii Ogbomọṣọ,
Ibadan, Ibarapa ati Oke-Ọgun ni wọn ti n dunkoko mọ awọn eeyan, ati pe awọn
agbegbe naa lẹgbẹ oṣelu PDP ti lẹnu ju wọn lọ.
Ọmọba Oyelade jẹ ko di mimọ pe
pẹlu awọn igbesẹ tẹgbẹ naa tun n gbe bayii, o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ẹrọ ti wọn
fi n ṣayẹwo kaadi idibo ti ko nii ṣiṣẹ ni wọn maa gbe wa sawọn agbegbe idibo
lọjọ naa, lati ma jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ri ibo di, gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lọjọ
Satide to kọja lọ nilẹ Awusa.
Nigba to n fọkan awọn araalu
balẹ, Ṣeyi Makinde sọ pe oun nigbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP yoo rọwọ mu gidi nitori
pe pẹlu maaki rẹpẹtẹ lawọn yoo fi la ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ naa, nitori naa, o ni
kawọn araalu jade lọpọ yanturu lati dibo lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment