Ẹ TUN WA A GBỌ O: WỌN NI ADANWO NLA KỌLU ALABI YELLOW - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 26, 2019

Ẹ TUN WA A GBỌ O: WỌN NI ADANWO NLA KỌLU ALABI YELLOW


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọlọwọ, inu ibanujẹ ọkan ni gbajumọ oṣere tiata nni, Samuel Oludayọ Akinpẹlu tọpọ awọn eeyan mọ si Alabi Yellow wa bayii, to si n ke gbajare sawọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ owo.

AWIKONKO gbọ pe nnkan ko dan mọnran mọ fun gbajugbaju oṣere tiata naa mọ, ko da a, ti wọn lawọn mọlẹbi ẹ gan an ti paa ti.

Kii ṣe iroyin mọ pe o ti ṣe diẹ ti Alabi Yellow ti kopa ninu fiimu agbelewo, nitori pe ṣe ni wọn sọ pe gbogbo awọn ti wọn ri ṣe daadaa ko pe e sinu fiimu wọn mọ

Ninu fọnran kan to n lọ kaakiri ori ayelujara bayii ni ọkunrin naa ti n sunkun fun iranlọwọ awọn araalu.

Bi ẹ ba wo fọnran naa, ẹ maa ri i pe inu yara ti Alabi Yellow n sun ko yatọ si ori akitan tawọn ẹranko buruku ti n jẹun. Yara naa ko yẹ ọmọ eniyan rara, depodepo gbajumọ oṣere tiata, tawọn aye n wo gẹgẹ bi awokọṣe.

E dakun, ẹ ran Alabi Yellow lọwọ o.

Lati ran Alabi Yellow lọwọ

Account Name: Dayọ Akinpẹlu
Bank: Unity Bank
Account Number: 0014193994
Phone Number: 070824109977

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI