Kani kii ṣe pe awọn oṣiṣẹ ojulalakanfinsori, iyẹn
Fijilante tijọba
ipinlẹ
Ogun, VSO ko sun asunpara ni, bo ya ọwọ wọn ko ba ma ti tẹ
baale ile ẹni
ọdun
mọkanlelaadọta
(51) kan, Ọlawale Ibrahim ti wọn
sọ
pe ko niṣẹ min in ju ko maa fi ayederu owo lu awọn
araalu ni jibiti lọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, orileede Benin, iyẹn
Kutọnu
ni wọn
sọ
pe Ọlawale
ti n ko ayederu owo naa wọ Naijiria, lati fi lu awọn
eeyan ni jibiti, ko too tun pada lọ ko min in wa.
AWIKONKO gbọ pe ọjọ Tọside ọsẹ to kọja lọ lọhun lọwọ palaba Ọlawale ti wọn nile Samuẹl, adugbo Baba Pupa, lagbegbe Sẹmẹ,
Badagry niluu Eko lo n gbe. Ilu kan ti wọn n pe ni Afuyẹ nitosi Ifọnyintẹdo, Idiroko lọwọ palaba ẹ ti segi ni nnkan bi aago mẹfa
irọlẹ ọjọ naa.
Nigba tọwọ maa tẹ ẹ, ibi to ti n paarọ owo lọwọ laṣiri ẹ ti tu pe ayederu owo lo kun ọwọ ẹ, to si fi n lu awọn
eeyan ni jibiti. Baṣiri
ẹ
si ẹe
tu lo gbiyanju lati salọ
ko too ko sọwọ awọn oṣiṣẹ Fijilante naa.
"Ẹ ṣe mi jẹjẹ, maa jẹwọ" l'orin ẹbẹ ti wọn loo mu sẸnu nigba ti okete Ẹ
ko raaye boru mọ wọn lọwọ, lẹsẹkẹsẹ lo jẹwọ pe o ti pẹ toun ti wa nidi iṣẹ naa, ati pe oun ni ọga
kan to n jẹ
Luwe, ẹni
to loo fi Kutọnu
ṣebugbe.
Nigba to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ
f'AWIKONKO, alukoro ẹgbẹ fijilante, Ọgbẹni Mọruf Yusuf sọ pe ẹgbẹrun kan naira lọna
mẹọo ati ẹgbẹrun mẹwa cefa lọna mẹsan an (8 pieces of #1,000 note and 9 pieces of 10,000
cefa) lowo tawọn
gba lọwọ ẹ loju ẹsẹ.
O wa a sọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe kawọn gbe Ọlawale lo teṣan ọlọpaa Idiroko lati tṣsiwaju
ninu iwadi wọn.
Gbogbo akitiyan lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lo ja si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment