DAPỌ ABIỌDUN YOO GBA IWE ẸRI LỌJỌBỌ TỌSIDE ỌSẸ YI - INEC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 26, 2019

DAPỌ ABIỌDUN YOO GBA IWE ẸRI LỌJỌBỌ TỌSIDE ỌSẸ YI - INEC

Gẹgẹ bi atẹjade ti alukoro ajọ eleto idibo, INEC nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ronald Dansu, fi ranṣẹ si AWIKONKO lai pẹ yii, o jẹ ko ye wa pe Tọside ọsẹ yi Oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọba Dapọ Abiọdun yoo gba iwe ẹri mo yege.

Dapọ Abiọdun ati igbakeji rẹ, Arabinrin Nọimọt Salakọ Oyedele ni wọn yoo gba iwe ẹri naa papọ gẹgẹ bi wọn ṣe jawe olubori nibi idibo gomina to kọja lọjọ kẹsan an oṣu yi.

Aago mọkanla aarọ ni eto gbigba iwe ẹri naa yoo bẹrẹ.

Yatọ si Ọmọba Dapọ Abiọdun ati igbakeji rẹ ti yoo gba iwe ẹri wọn, AWIKONKO tun gbọ pe gbogbo awọn ti wọn wọle gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun patapata naa yoo gba iwe ẹri ti wọn.

Ọgbẹni Dansu fi ye wa pe aago kan ọsan lawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yoo bẹrẹ gbigba iwe ẹri tiwọn bakan naa ni olu ileeṣẹ INEC to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI