Yatọ si pe wọn gbe oṣuba kare
fun Gomina Amosun, bẹẹ ni wọn tun fi ẹbun ta a lọrẹ fun bo ṣe gbegba oroke nibi
idibo tawọn aṣofin agba niluu Abuja, eyi to kọja lọ lọhun.
Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ
naa, Kọmureedi Wale Adewumi sọ pe kii ṣe pe awọn dee de wa a fi ẹbun ta Gomina Amosun lọrẹ, ṣugbọn
nitori pe awọn mọ riri ipa to ko nipa idagbasoke ipinlẹ naa, ati paapaa bo ṣe
jawe olubori nibi idibo Sẹnetọ to kọja lọ.
Gomina Amosun fẹmi imoore han,
to si loun dupẹ gidigidi lọwọ awọn akọroyin ipinlẹ naa, latari bi wọn ṣe n gbe
ijọba oun larugẹ.
No comments:
Post a Comment