Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi iroyin lo ti jade sori ayelujara latari iku gbajumọ oṣere tiata nni, Oloye Alfred Rotimi Popoọla, ṣugbọn ti AWIKONKO ti pada ṣewadi naa daadaa.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi iroyin lo ti jade sori ayelujara latari iku gbajumọ oṣere tiata nni, Oloye Alfred Rotimi Popoọla, ṣugbọn ti AWIKONKO ti pada ṣewadi naa daadaa.
Ṣe ni ariwo ibanujẹ nla tun sọ lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba
ti ọkan lara awọn agba ọjẹ nidi iṣẹ tiata ti
TAMPAN nipinlẹ Ogun, Oloye Alfred Rotimi Popoọla dagbere
faye laarọ ọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi.
Bawọn kan ṣe n sọ pe iku
gbajumọ oṣere tiata naa kii ṣoju lasan, o
lọwọ aye ninu, bẹẹ lawọn kan n sọ pe amuwa Ọlọrun ni, tawọn min in si
n sọ pe akufa to n ṣẹlẹ lagbo oṣere tiata lo
fa a.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni lati bi
ọsẹ mẹta sẹyin ni
Alfred tọpọ awọn eeyan tun
n pe ni Ilu Venture fi ẹsẹ kọ, ti ẹsẹ naa ko si jẹ
ko gbadun
latigba naa, eyi ti wọn loo da a jokoo sile, ti ko le jade lọ sibi
kankan.
Ẹsẹ naa la gbọ pe o ba a
ja titi ti ko fi yọju sibi ipade tẹgbẹ osere
TAMPAN ṣe, paapaa nibi ti wọn ti gbe ọpa aṣẹ fawọn oloye
tuntun niluu Abẹokuta, eyi to waye lọjọ kọkanlelogun oṣu keji to kọja yi.
Nigba
to maa ku, a gbọ pe ẹsẹ naa ni won
lo o sọ pe o n dun oun gidi, ko si pẹ ni wọn loo tun bẹrẹ sii sọ pe ori n fọ oun, ti wọn si sare
gbe e lọ si ọsibitu adani
kan ladugbo to n gbe ni Ibẹrẹkodo, nijọba ibilẹ Abẹokuta North,
iyẹn lọjọ Mọnde ọsẹ to kọja yi.
AWIKONKO
gbọ pe nigba to maa di aarọ Tuside ni wọn loo bẹrẹ sii sunkun
pe ori to n fọ oun naa ti kọja sisọ, eyi lo mu
ki wọn tun sare gbe e lọ si FMC lati
tọju ẹ, bi wọn ṣe gbe e de bẹ ni wọn ti bẹrẹ sii tọju ẹ.
Ohun
ta a tun gbọ ni pe nigba to maa di ọwọ irọlẹ, ṣe lọrọ naa
tun yiwọ ni ọsibitu FMC
to wa ladugbo Idi-Aba, to muu ki wọn gbe ẹrọ afẹfẹ igbalode (oxygen)
sii nimu nitori to ti wọ kọma (coma).
Eyi
ni wọn ṣe titi to fi di aarọ kutu ọjọ Wẹside to dagbere pe o
digboṣe. Ere ni wọn kọkọ pe e,
afigba ti wọn lawọn nọọsi tare oku ẹ
si mọṣuari pe ẹmi ti kuro
lara ẹ, lo mu kariwo sọ.
Ẹsẹ ko gbero lọsibitu FMC lọjọ naa biroyin
naa ṣe tan sita, ko da a ti wọn lawọn alaṣẹ
ọsibitu naa paṣẹ fawọn sikiọriti ẹnu geeti pe ẹnikẹni ko gbọdọ wọle mọ, ṣugbọn ti wọn pada ṣii nitori awọn ti wọn waa gba itọju nibẹ.
Lẹsẹkẹsẹ
la gbọ pe wọn ti bẹrẹ ipalẹmọ isinku ẹ, eyi ti wọn ṣe ni ṣọọṣi to n lọ, iyẹn St Jude
Cathedral to wa ladugbo Ibẹrẹkodo nibẹ. Ẹsẹ ko gbero
ninu ṣọọṣi naa nigba ti wọn n ṣe ẹyẹ ikẹyin fun.
Nigba
to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Oloye Ṣeyi Crown to
ṣalaye bi
gbogbo nnkan naa ṣe lọ jẹ ko di mimọ pe gbogbo
eto ati ẹyẹ ikẹyin to yẹ ki ẹgbẹ oṣere TAMPAN ṣe lawọn ti ṣe fun un lọjọ Tọside ti wọn si n naa, ati pe awọn lawọn lọọ gbe oku ẹ ni mọṣuari.
“Ẹsẹ kekere kan lo fi rọ, a ṣe inauguration TAMPAN lọjọ kọkanlelogun oṣu to kọja yi, igba ti a ko rii la fi pe e lati beere idi ti ko fi yọju, ko to wa a ṣalaye pe ẹsẹ kan toun fi rọ lo n ba oun ja, toun ko le jade. Lọjọ idibo apapọ to kọja lọ, o wa ladugbo ẹ, nitori pe oun ni adari ẹgbẹ oṣelu ADC ladugbo ẹ.
“Nigba
to tun di ọjọ Mọnde lo sọ pe ori kan
n fọ oun, tawọn ẹbi ẹ si gbe e lọ si ọsibitu kan
ladugbo wọn nibi ti wọn da a duro
sii. Aarọ Tuside lo tun sọ pe ori naa
ti kọja nnkan ti wọn le tọju nibẹ, eyi lo mu
ki dọkita ọsibitu naa sọ pe ki wọn maa gbe e
lọ si FMC.
“Igba
igba to maa to irọlẹ lo wọ kọma, ni wọn gbe ẹrọ afẹfẹ igbalode, iyẹn oxygen si i nimu, nigba to maa di aarọ Wẹside lo dake.
Gbogbo eto to yẹ ka ṣe fun un la
ti ṣe. Mi o nigbagbọ pe eeyan lo
pa a, to ba si jẹ eeyan lo wa nidi ẹ, o ku ẹni naa pẹlu Ọlọrun.”
Bo tilẹ jẹ pe a ko mọ iye iyawo ati ọmọ ti
Oloogbe naa fi silẹ lọ, ṣugbọn AWIKONKO gbọ pe iyawo ẹ mẹta atawọn ọmọ ni wọn wa nibi isinku lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment