AṢIRI AHMED TO N TA GOOLU TU SỌWỌ EFCC L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 4, 2019

AṢIRI AHMED TO N TA GOOLU TU SỌWỌ EFCC L'EKO

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Titi dasiko ta ṣakojọpọ iroyin yi tan la ko tii gbo pe Mannir Hamza Ahmed ti wọn ka goolu olowo iyebiye lọwọ ẹ lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ti jẹwọ fun ajo EFCC to n gbogun ti iwa iṣowo kumọkumọ.

Papakọ ofurufu tiluu Eko la gbọ pe aṣiri Ahmed ti tu latari olobo ti wọn ta awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC naa.

Orileede UAE, niluu Dubai la gbọ pe o ko awọn goolu ti wọn ko tii fọ naa lọ lati lọọ ta a.

Goolu tuntun mọkandinlogun ni wọn ka mọ ọ lọwọ, ta a si gbọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ẹrọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI